Ọkunrin yii ma daju o, awọn alaisan to wa lọsibitu lo maa n lu ni jibiti n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Pipa ni wọn iba pa ọkunrin ẹni ogoji (40) ọdun kan, Bukọla Adewale, sileewosan ijọba ipinlẹ Ọyọ, iyẹn Adeọyọ State Hospital, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejilelogun (22), oṣu kẹrin, ọdun 2024 yii, bi ki i baa ṣe pe awọn oṣiṣẹ eleto aabo ilẹ Yoruba, Amọtẹkun, tete de sibẹ lati gba a silẹ lọwọ awọn ẹruuku.

Bukọla ti wọn gba silẹ yii, ẹruuku loun gan-an funra rẹ, nitori bo tilẹ jẹ pe nitori iwa jibiti ni wọn ṣe n lu u bii ko ku, afurasi apaayan la ba pe oun gan-an funra rẹ, nitori Ọlọrun lo mọ iye eeyan ti oun paapaa ti ran lọ sọrun nitori iṣẹ jibiti to yan laayo.

Eeyan kan ko tun gbọdọ ya ọdaju ju ọkunrin to pera ẹ lọmọ bibi ilu Adà, nipinlẹ Ọṣun, yii lọ, nitori niṣe lo maa n ti ileewosan nla kan bọ sikeji. Awọn ti ko ba si lalaafia rara, tabi ti ẹmi ti fẹẹ ibọ lara wọn patapata loun maa n pa lẹkun jaye.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, awọn alaisan to ba n jẹrora loju mejeeji tabi ti wọn n pọ̀kàkà iku lọwọ lo maa n lọọ ba. O maa dibọn bii oṣiṣẹ ileewosan, yoo si ṣe aajo awọn alaisan to n jẹrora taanu taanu, to bẹẹ ti awọn onitọhun yoo fi ro pe ẹlẹyinju aanu eeyan kan to ṣetan lati ran awọn lọwọ ni i ṣe, nitori kia ni yoo ti gba  kaadi ti wọn fẹẹ fi ri dokita lọwọ wọn, ti yoo si ṣeleri lati ba wọn ṣe gbogbo wahala to yẹ ki wọn ṣe ṣaaju ati lẹyin ti wọn ba ri dokita tan.

Gbogbo iṣẹ ti wọn ba ran an patapata

lo maa n jẹ tidunnu-tidunnu,  awọn alaisan yoo si ti maa dupẹ lọwọ ẹ gẹgẹ bii oloore wọn. Ṣugbọn nibi ti gbogbo ọmọluabi rẹ mọ naa niyẹn, bi wọn ba ti fun un lowo lati lọọ ra oogun wa bayii, nigba naa ni wọn yoo too mọ iru eeyan to jẹ. Niṣe ni jagunlabi maa gbe wọn lowo sa lọ.

Iṣẹ ti Bukọla yan laayo ree lati bii ọdun meji sẹyin ko too di pe ọwọ palaba ẹ segi lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrindilogun (16), oṣu Kẹrin, ọdun 2024 ta a wa yii, nibi to ti n gbiyanju lati ti tun lu awọn alaisan meji ni jibiti lọjọ kan naa, lasiko kan naa. Iya kan to gbe ọmọ ẹ lọ sileewosan fun itọju ati baba kan, Oloye Wahab Aiki Aloko, to jẹ ijoye atata nilẹ Ibadan, ni jagunlabi tun fẹẹ pa lẹkun ki ọwọ palaba ẹ too segi.

O ti gba kaadi lọwọ baba oloye yii bii ẹni to fẹẹ ran onitọhun lọwọ pẹlu erongba lati pada waa gbowo lọwọ baba naa, nibi to si ti n gbowo lọwọ eyi iyalọmọ lọwọ, lọkan ninu awọn oṣiṣẹ ileewosan ọhun to ti n wa a latigba to ti ṣe bẹẹ lu alaisan kan ni jibiti nileewosan naa ri i.

Bi iyẹn ṣe pariwo ole le e lori lawọn eeyan ṣuru bo o, ti wọn si bẹrẹ si i lu u tibinu tibinu. Wọn iba si lu u pa bi ko ṣe awọn Amọtẹkun ti wọn tete debẹ lati gba a silẹ lọwọ iya àjẹkúdórógbó.

Oloye Aiki, to jẹ Baalẹ Àgbẹ̀, nijọba ibilẹ Ariwa Ibadan, ṣalaye bo ṣe ko sọwọ ọdaju ọkunrin naa, o ni, “ẹsẹ mi lo wu ti mo fi lọ sileewosan Adeọyọ. Bi mo ṣe n bọ lati ibi ti mo ti gba esi ayẹwo ti mo ṣe lọmọkunrin yẹn pade mi, to ni ki n waa jokoo, oun yoo ran mi lọwọ, ki n ma baa fi inira ṣe ohunkohun.

“O gba kaadi lọwọ mi, o loun yoo ba mi ri dokita fun akọsilẹ oogun ti mo nilo. Mo ro pe o fẹẹ ran mi lọwọ ni, laimọ pe niṣe lo fẹẹ lu mi ni jibiti. Ọlọrun lo yọ mi, to ni ki ẹni to da a mọ ri i, tọwọ fi tẹ ẹ”.

Nigba to n fidi iroyin yii mulẹ, Igbakeji ọga agba awọn Amọtẹkun nipinlẹ Ọyọ, Ọgbẹni Kazeem Babalọla Akinro, ṣalaye pe, “Eyi kọ nigba akọkọ to (Bukọla) maa hu iru iwa yii.

“Gẹgẹ bii iwadii wa, o ti maa n ṣe bẹẹ tẹlẹ ri nileewosan UCH, ko too di pe aṣiri ẹ tu, ti wọn si fofin de e pe ko ko gbọdọ wa sọdọ awọn mọ.

“Awọn ti ailera wọn ba lagbara lo maa n lọọ ba, yoo gba kaadi wọn pe oun fẹẹ ran wọn lọwọ láti ri dokita. Lẹyin ti dokita ba ti kọ oogun fun wọn tan, yoo lọọ ba wọn beere iye ti wọn n ta awọn oogun naa. Ṣugbọn ti wọn ba ti fun un lowo oogun bayii, nibẹ ni ibasepọ wọn yoo pari si, nitori latigba naa ni wọn ko ti ni i foju kan an mọ, niṣe lo maa gbówó wọn sa lọ.

“Lori eyi ta a fi mu un yii, awọn ọga ileewosan Adeọyọ ni wọn pe wa pe ẹnikan n lu awọn alaisan ni jibiti. Ori ibi ti wọn ti n lu u lọwọ lawọn eeyan wa ba wọn ti wọn fi gba a silẹ.

“Nigba ta a mu un de akata wa, o kọkọ purọ pe oun ko mọ nnkan kan nipa ẹsun ta a mu oun fun. Ṣugbọn nigba a fi awọn ẹri to wa lọwọ wa han an lo jẹwọ pe loootọ loun maa n lu awọn alaisan ni jibiti.

O ni alaisan meji loun lu ni jibiti lọjọ yẹn, oun ti gba ẹgbẹrun mẹwaa (N10,000) Naira lọwọ ẹni kan, oun gba ẹgbẹrun mejila Naira lọwọ ẹnì kejì. Bẹẹ naa lo gba ẹgbẹrun lọna ogoji Naira lọwọ ẹni kan naa nileewosan ijọba ipinlẹ Ọyọ to wa ni Ring Road, nigba kan ri.

“Iru nnkan bẹẹ naa lo tun fẹẹ ṣe lọjọ Tusidee to kọja tọwọ fi tẹ ẹ”.

Ọkan ninu awọn ọga ileewosan Adeọyọ, ṣalaye pe, “Ni nnkan bii oṣu mẹfa sẹyin la ri i pe awọn alaisan mi-in maa n sunkun, wọn a a ni ẹnikan ti gba owo to yẹ ki awọn fi ṣe ayẹwo tabi owo ti awọn fẹẹ fi ra oogun lọwọ awọn.

“Nṣe la maa n pada ba wọn ṣayẹwo yẹn lọfẹẹ, nigba ta a ba ri i pe wọn o lowo mi-in ti wọn maa fi ṣayẹwo lọwọ mọ. Ni nnkan bii aago mejila aabọ ọjọ Tusidee la deede n gbọ, ole! Ole! Ole! Bo ṣe bẹrẹ si i sa lọ niyẹn, o n sa lọ sọna ibi geeti to wa lọna mọ́ṣúárì, ṣugbọn Ọlọrun mu un, wọn ko si geeti ibẹ silẹ, iyẹn lo jẹ ki awọn eeyan ri i mu”.

Ninu ọrọ tiẹ, afurasi onijibiti yii jẹwọ pe ileewosan mẹta ọtọọtọ, ileewosan UCH, ileewosan Adeọyọ to wa ni Ring Road, n’Ibadan, ati ileewosan Adeọyọ to wa laduugbo Yemẹtu, n’Ibadan, loun ti maa n pa awọn alaisan lẹkun jaye.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Lati kekere ni mo ti kuro lọdọ awọn obi mi, ti mo n gbe pẹlu ara ṣọọṣi ẹgbọn mi kan n’Ibadan nibi, nítorí lati kekere ni mo ti ya ọmọ lile, to jẹ pe  apa awọn obi mi ko ka mi.

“Ẹgbọn mi fi mi sẹnu ẹkọṣẹ, o si ra irin-iṣẹ fun mi, ṣugbọn mo sa kuro lẹnu ẹkọṣẹ, mo lọ si Sẹ̀mẹ̀ Bọdà, nibi mo ti n fi ẹyin pọn apo irẹsi wọle fawọn onifayawọ. Ọdun kan aabọ ni mo lo nibẹ ti mo fi pada s’Ibadan lati waa ma lu awọn alaisan ni jibiti.

“Ileewosan UCH ni mo ti bẹrẹ. Mo lọọ ba obinrin kan to gbe eeyan rẹ lọ  si ẹka ti wọn ti n tọju awọn alaisan to nilo itọju kiakia. Mo ba a kaaanu, mo si ṣeleri lati ran an lọwọ. Obinrin yẹn dupẹ lọwọ mi gan-an, o waa ni ki n jọọ, ki n lọọ ba oun ra oogun wa. Ẹgbẹrun mejilelaaadọta (N52,000) lo fun mi lati fi ra awọn oogun yẹn. Ṣugbọn mi o pada sọdọ rẹ mọ lẹyin ti mo gbowo yẹn tan, niṣe ni mo gbe owo yẹn sa lọ.

“Lọjọ kẹta ti mo tun pada lọ sibẹ lẹni ti mo gbowo lọwọ ẹ yẹn ri mi, ti wọn fa mi le awọn ọlọpaa lọwọ ni teṣan ọlọpaa Yemẹtu (n’Ibadan).

“Ẹgbọn mi lo da owo ti mo gba lọwọ obinrin yẹn pada fun un. Awọn ara UCH ya fidio mi, wọn si kilọ fun mi pe mi o gbọdọ wọ inu ọgba awọn mọ.

Bi mo ṣe dẹni to n lọ sileewosan Adeọyọ, ni Yemẹtu niyẹn, ati ileewosan Adeọyọ to wa ni Ring Road. Ẹgbẹrun lọna ogoji Naira (₦40,000) ni mo gba lọwọ awọn ẹbi alaisan kan ni Ring Road. Owo ti alaisan yẹn fẹẹ fi ṣayẹwo ni, ṣugbọn niṣe ni mo gbowo yẹn sa lọ”.

Lori eyi to ṣe tọwọ fi tẹ ẹ, ọkunrin afurasi ọdaran yii fidi ẹ mulẹ pe, “eeyan meji ni mo gbowo lọwọ wọn l’Adeọyọ to wa ni Yemẹtu. ti wọn fi mu mi. Mo gba ẹgbẹrun mejila Naira lọwọ ẹni kan, ẹgbẹrun mẹwaa Naira lọwọ ẹni keji”.

Ni bayii, awọn Amọtẹkun ti fa ọkunrin naa le ọlọpaa lọwọ fun iwadii siwaju si i, ati fun ijiya to ba tọ si i labẹ ofin.

 

Leave a Reply