Ẹgbẹ alagbata epo ti sọrọ: O ṣi maa to ọsẹ meji si i ki ọwọngogo epo yii too rọlẹ!

Faith Adebọla

Ẹgbẹ awọn alagbata epo rọbi nilẹ wa, Independent Petroleum Marketers Association of Nigeria (IPMAN), ti tubọ da omi tutu sọkan awọn araalu, paapaa awọn ti wọn n reti pe ki wahala ọwọngogo epo bẹntiroolu to gbode kan lẹnu ọjọ mẹta yii, ati iṣoro owo ọkọ to gbẹnu soke tete walẹ, wọn ni bi iṣoro yii yoo ba yanju, ki i ṣe ni kiakia yii, wọn lo maa to ọsẹ meji, iyẹn bi ko ba ju bẹẹ lọ, ki nnkan too pada bọ sipo.

Alukoro ẹgbẹ awọn alagbata ọhun, Ọgbẹni Chinedu Ukadike, lo sọrọ yii di mimọ laṣalẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, niluu Abuja, fawọn oniroyin.

Ọkunrin naa ni to ba jẹ ododo ọrọ lawọn eeyan fẹẹ gbọ, ohun to ṣokunfa ọwọngogo epo bẹntiroolu ati laasigbo tawọn araalu n koju bayii ko ṣeyin pe epo ko si niluu, o lepo ko wọle lati ilẹ okeere tawọn ti lọọ fọ ọ wa ni.

Njẹ ki lo fa a tepo ko wọle, o mẹnu ba oriṣiiriṣii ipenija bii awọn ile ifọpo ilu oyinbo ti wọn n ṣe atunṣe si lọwọ, ipenija kiko ọja wọle lati ẹyin odi, ati bii iṣoro tawọn alagbata n koju nigba ti wọn ba fẹẹ ṣe atungba lansẹnsi wọn lọdọọdun lọdọ ajọ Nigeria Midstream Downstream Petroleum Regulatory Authority (NMDPRA), o ni ilana kinni naa ti falẹ ju, awọn ko si lọna abayọ mi-in ju ki wọn mu suuru lọ.

Ukadike ṣalaye pe ninu nnkan bii ẹgbẹrun mẹẹẹdogun (15,000) alagbata epo to wa nilẹ yii, ẹgbẹrun kan pere lo ṣi ri lansẹnsi iṣiṣẹ tọdun yii gba lọdọ ajọ NMDPRA, agbara kaka si ni wọn fi ri i gba. O ni nibi ti eeyan kan ba ti n ṣiṣẹ to yẹ keeyan mẹẹẹdogun ṣe, ko sọgbọn ti tito lori ila lai lopin ko ni i ṣẹlẹ nileepo.

O tun fi kun un pe ileeṣẹ NNPC, to jẹ awọn lo n lewaju ninu kiko awọn eroja epo rọbi wọlu naa n koju awọn ipenija gidigidi, lara ẹ ni bi awọn ọkọ oju-omi agbepo wọn ṣe n ni idiwọ kan sikeji, ati ijakulẹ latọdọ awọn alaba-dowo-pọ agbaye gbogbo.

Amọ ṣa o, ọkunrin naa sọ pe oun nigbọkanle ninu ọrọ ati eto ti ọga agba ileeṣẹ NNPC ṣe lati ri i pe epo ti yoo to fun oṣu kan yoo wọle lai ṣọsẹ. O ni bi eyi ba ṣẹlẹ, wahala ọwọngogo ati inira yii yoo dinku, ṣugbọn o ni yoo ṣi to ọsẹ meji, tori kinni naa ki i sare parẹ bẹẹ, o ni lati bii ọsẹ kan laraalu ti maa bẹrẹ si i ri iyatọ, titi to fi maa rọlẹ lọṣẹ keji, bi gbogbo nnkan ba lọ bo ṣe yẹ.

Leave a Reply