Egboogi oloro ni Danjuma n gbe lọ sorileede Italy tọwọ fi tẹ ẹ

Adewale Adeoye

Ọdọ awọn alaṣẹ ajọ to n gbogun ti gbigbe ati lilo egboogi oloro lorileede yii, ‘National Drug Law Enforcement Agency’ (NDLEA), ẹka tipinlẹ Eko, ni baale ile kan, Ọgbẹni Danjuma  Yahaya Oturah, wa. O n ran awọn ajọ ọhun lọwọ ninu iwadii wọn nipa ẹsun ti wọn fi kan an. Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun yii, lawọn oṣiṣẹ ajọ naa fọwọ ofin mu un ni geeti C, ni papakọ ofurufu ‘Murtala Muhammad International Airport’ to wa niluu Ikeja, nipinlẹ Eko, lasiko to fẹẹ gbe egboogi oloro Tramadol lọ sorileede Italy.

ALAROYE gbọ pe ọkọ baalu Ethiopian Airlines, lo fẹẹ ba lọ sorileede Italy, ṣugbọn ọwọ awọn agbofinro tẹ ẹ nigba to ku diẹ ko rapala wọ’nu ọkọ baalu naa.

Alukoro ajọ ọhun, Ọgbẹni Fẹmi Babafẹmi, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun yii, sọ pe inu aṣọ awọn obinrin, ẹgusi lilọ atawọn oniruuru ounjẹ ibilẹ ni afurasi ọdaran ọhun tọju awọn egboogi oloro naa si kọwọ too tẹ ẹ.

Alukoro ni ọdọ awọn ti afurasi ọdaran ọhun wa lo ti jẹwọ pe owo nla ni wọn ṣeleri foun, boun ba le gbe egbogi oloro naa de Italy.

O ni wọn maa too foju rẹ bale-ẹjọ.

 

Leave a Reply