Nitori ọdun Oro, isede yoo wa fawọn obinrin niluu Ikorodu lọjọ yii

Adewale Adeoye

Ni bayii, gbogbo eto ti to pata, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Karun-un, ọdun 2024 yii, ni awọn oniṣẹṣe niluu Ikorodu, nipinlẹ Eko lawọn maa ṣe Oro laarin ilu naa, ti wọn si ti kilọ fawọn obinrin atawon ajoji gbogbo ti wọn ki i ṣe ọmọ oniluu pe wọn ko gbọdọ jade sita lasiko ayẹyẹ ọhun.

Ọba Ayangburen tilu Ikorodu, Ọba Ṣotobi, ti rọ awọn obinrin pe ki wọn jokoo sile wọn lasiko ti wọn ba n ṣọdun Oro naa lọwọ titi dọjọ keji ti wọn maa fi pari gbogbo eto naa pata.

Atejade kan to wa lati aafin Ọba Ayangburẹn, eyi ti Ọba Ṣotobi funra rẹ fọwọ si, eyi ti ẹda rẹ tẹ ALAROYE lọwọ ni wọn ti rọ awọn alaṣẹ ileewosan ijọba, ‘Ikorodu General Hospital’, to wa niluu Ikorodu, pe ki wọn faaye gba awọn oṣiṣẹ wọn ti wọn jẹ obinrin pe ki wọn ma ṣe wa sibi iṣẹ lasiko ti etutu naa n lọ lọwọ laarin ilu, ki idarudapọ ma baa waye.

Atẹjade ọhun, eyi ti wọn fi ranṣẹ sawọn alaṣẹ ileewosan ọhun lọ bayii pe, ‘A n fi asiko yii sọ pe etutu ati ajọdun ọdun Oro wa niluu Ikorodu, tọdun yii maa waye lọjọ Tọsidee, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Karun-un, ọdun yii. Gẹgẹ bii iṣe wa lọdọọdun, awọn obinrin ati ajoji ti wọn ki i ṣe ọmọ ilu ko gbọdọ rin kaakiri igberiko, paapaa ju lọ niluu Ikorodu, rara,  a n rọ yin pe kẹ ẹ ba wa fara da a diẹ, bo tilẹ jẹ pe igbesẹ yii le pa okoowo yin lara’.

Ọdun Oro ki i ṣe ajoji nilẹ Yoruba rara, awọn ọkunrin ti wọn jẹ ọmọ ilu ni wọn saaba maa n jade lasiko ọdun naa, iṣẹṣe ko gba pe kawọn obinrin jade sita lasiko ayẹyẹ ọdun Oro rara. Eyi lo fa a tawọn alaṣẹ ilu Ikorodu ṣe tete kede bayii pe, ki awọn obinrin atawọn ajoji maa gbaradi silẹ fun ti ọdun yii to maa waye lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Karun-un, ọdun yii.

Leave a Reply