Ẹ ma f’ọkan si i, ijọba Tinubu ko lagbara lati tun ọrọ-aje Naijiria yii ṣe o – Suswam

Faith Adebọla

Gomina tẹlẹri nipinlẹ Benue, Sẹnetọ Gabriel Suswam, ti sọ oju abẹ nikoo lori iṣejọba Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu to wa lori aleefa lọwọlọwọ, baba naa ni bi awọn ọmọ Naijiria ba n reti ki ọrọ-aje burẹkẹ, ki nnkan si rọṣọmu lasiko Tinubu yii, ireti ofo lasan niru ireti bẹẹ, tori ootọ ibẹ ni pe ijọba yii ko lagbara to, ko si lawọn ohun amuyẹ ti yoo fi le ṣatunṣe gidi si ọrọ-aje orileede yii, o lẹmi-in ijọba yii o gbe e rara ni.

Suswan, to tun ṣoju awọn eeyan ẹkun idibo Ariwa/Ila-Oorun ipinlẹ Benue lẹyin ọdun mẹjọ rẹ nipo gomina nileegbimọ aṣofin agba, sọrọ yii lopin ọsẹ to kọja, iyẹn ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹrin, ọdun yii, lasiko to n kopa lori eto ileeṣẹ amohun-maworan Channels kan niluu Abuja.

Suswan sọ pe: “O ṣe ni laaanu pe latigba iṣejọba Muhammadu Buhari, ariwo ‘ayipada’ (Change) ni wọn pa. Ko sẹni to beere pe iru ayipada wo lo fẹẹ mu wa, ṣe ayipada si rere ni abi apada-si-buruku. Gbogbo nnkan toju wa ri laarin ọdun mẹjọ iṣejọba yẹn lo ba wa di idi ohun toju wa n kan lasiko yii, tori o fẹrẹ jẹ gbogbo ipilẹ ti ẹgbẹ oṣelu PDP fi lelẹ ni wọn fa tu, ti awọn Buhari wo danu. Bẹẹ la bẹrẹ irinajo sinu ọgbun ainisalẹ.

Ipo ti orileede yii wa ni ti ọrọ-aje ko ṣee maa fete kan, o si tun ṣe ni laaanu pe ijọba to tẹle ti Buhari, iyẹn ijọba Tinubu yii, ko ni ohun ti yoo fi ṣe e ti ayipada rere yoo fi ba ọrọ-aje orileede yii. Ẹ ma tiẹ fọkan si i rara ni, gbogbo ilana ati eto ọrọ-aje ti wọn n gun le lo tubọ fihan pe ojuutu si ipọnju yii ko si nikapa wọn rara.

“Ẹ jẹ ki n fun yin ni apẹẹrẹ. Tinubu yọ owo iranwọ ori epo bẹntiroolu lọjọ kin-in-ni to gori aleefa, lẹyin naa lo patẹ owo ilẹ wa, Naira, sọja agbaye, o fi kun owo-ele ti wọn ya awọn olokoowo. Ni bayii, wọn tun ti fi kun owo ina ẹlẹntiriiki. Bawo ni araalu ṣe fẹẹ gbaye-gbadun labẹ awọn ajaga eto ọrọ-aje to wuwo buruku ti wọn gbe ka wọn lejika wọnyi? Lakọọkọ, iṣoro nla kan ni sọbusidi jẹ, tori o nipa lori owo ọkọ, owo idokoowo, owo tawọn onileeṣẹ fi n ṣe ọja jade, tori gbogbo nnkan wọnyi lo rọ mọ ipese agbara, wọn si ti yọ ọ danu. Tori bẹẹ, ẹni to n ta nnkan tẹnu n jẹ, to jẹ ẹgbẹrun marun-un Naira (N5,000) lo fi n ko ọja rẹ laarin ilu Abuja ti waa n na ẹgbẹrun mẹẹẹdogun Naira (N15,000) bayii, nibo lẹ ro pe inawo naa maa kangun si? Awọn to fẹẹ raja ni. Iyẹn lo mu ki ọwọngogo ọja roke lala bayii, a o gbọ iru ẹ ri nilẹ yii.

O ya ẹ jẹ ki n sọrọ lori ti owo Naira. Ko si orileede eyikeyii lagbaaye ti wọn ba patẹ owo wọn bi awa ṣe patẹ Naira yii, to jẹ pe bi kara kata agbaye ba ṣe ri lo n pinnu iye ta a maa maa ṣẹ Naira si dọla atawọn owo agbaye mi-in, ti irufẹ orileede bẹẹ le yọ bọ lọwọ ọrọ-aje to wogba, ko sọgbọn ẹ. Bẹẹ ba ri orileede tiru ẹ ti ṣẹlẹ, ti wọn si yebọ, ẹ sọ ọ fun mi, ṣe awọn orileede Latin Amerika ni abi nibo? Lawọn ọdun 1980 si 1990 siwaju, lajori ohun to ṣakoba fawọn orileede Latin Amẹrika ni pe wọn ṣepinnu ti ko bọgbọn mu nipa ọrọ-aje ati owo wọn, wọn si geka abamọ jẹ, iru ẹ naa leyi ta a n ṣe bayii lori owo Naira, yiyọ sọbusidi lori igba, lori awo, lori tibi, lori tọhun, abọ rẹ ko ni i daa rara.”

Bẹẹ ni gomina tẹlẹri naa sọ o.

Leave a Reply