Ortom gba Yahaya Bello nimọran: Jade sita nibi to o ba wa, yee doju ti awa gomina

Faith Adebọla 

Owe ẹru kan ni i mu’ni bu igba ẹru ti Yoruba maa n pa lo wọ ọrọ amọran pataki ti Gomina ana nipinlẹ Benue, Samuel Ortom, ti gba akẹgbẹ rẹ, toun naa jẹ gomina ana nipinlẹ Kogi, Yahaya Bello. Ortom ti sọ fọkunrin naa pe ko jade bọ si gbangba nibikibi to ba wa, ko yee sa pamọ kiri, ko waa ṣalaye ara ẹ ati bi ẹsun ti EFCC fi kan an wọnyi ṣe jẹ, tori iwa isansa rẹ ti fẹẹ di nnkan abuku fun gbogbo awọn ti wọn ti ṣe gomina ri bii tirẹ, o lo ti n jẹ kawọn eeyan maa foju tẹmbẹlu awọn kaakiri.

Nibi ayẹyẹ ijọsin kan to waye lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹrin yii, nile ijọsin Ridiimu, iyẹn The Redeemed Christian Church of God, to wa niluu Makurdi, nipinlẹ Benue, eyi ti Samuel Ortom jẹ alejo pataki nibẹ, lo ti sọrọ ikilọ yii.

Ortom ni o yẹ k’oun sọ ootọ ọrọ fun ọrẹ oun ati akẹgbẹ oun kan, Yahaya Bello, o ni bo ṣe lọọ fara sinko sibi kan yii, ti ko fẹẹ yọju si EFCC, ti ko si ṣalaye gunmọ kan lati wẹ ara ẹ mọ lori ẹsun jibiti lilu, ṣiṣe owo ilu mọkumọku lasiko iṣejọba rẹ ti wọn fi kan an, o ni iwa naa ko daa rara, tori abuku rẹ ki i ṣe ti Yahaya Bello nikan, gbogbo awọn ti wọn ti di ipo gomina mu tẹlẹri nibi gbogbo lorileede yii ni ẹgbin naa ba, ati pe sisapamọ ti Bello sa pamọ yii yoo wulẹ maa mu ọrọ naa le koko si i ni.

Ortom ni: “Mo fẹẹ lo anfaani yii lati gba aburo mi ati ọrẹ mi, Gomina Yahaya Bello, lamọran, pe ko ma yẹpẹrẹ awa ta a ti ṣe gomina ri nilẹ yii.

“O o nilo lati sa pamọ. O o nilo lati ṣediwọ fawọn to fẹẹ mu ẹ, tabi ṣe ẹ bakan. Lọ sibẹ, lọ sọdọ wọn, da wọn lohun ohun ti wọn ba bi ẹ. Eeyan bii tiẹ naa lawọn ẹṣọ EFCC, ti wọn ba fẹẹ ṣewadii kan, ṣebi ofin ti wa nilẹ fun gbogbo eeyan.

“Mo ti ṣapa lati ba a sọrọ lori aago, ṣugbọn mi o ri i ba sọrọ. Mo gbiyanju lati ran awọn to wa ni sakaani rẹ si i, amọ ko ṣee ṣe, tori ẹ ni mo fi sọrọ akiyesi yii. Nibikibi yoowu ko o wa, to o ba le gbọ mi, ọpẹ ni pe awọn oniroyin tiẹ wa nibi loni-in, jade si gbangba o,” gẹgẹ bo ṣe wi.

Ẹ oo ranti pe gẹrẹ ti Samuel Ortom kuro lori ipo gomina ni oṣu Karun-un, ọdun 2023, ni ajọ to n gbogun ti ṣiṣe owo ilu mọkumọku ati iwa jibiti lilu nni, Economic and Financial Crimes Commission (EFCC), ti ranṣẹ si i pe ko foju kan awọn lọfiisi wọn, Ortom si yọju si wọn loṣu Kẹfa, ọdun naa, wọn fi ibeere po o nifun pọ, wọn si yọnda rẹ lẹyin akoko diẹ.

Bakan naa ni gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Ayọdele Fayoṣe naa ṣe nigba ti EFCC ranṣẹ pe e, funra rẹ lo lọ sibẹ, to si gbe ẹni dani pe aibaa mọ, wọn le fẹe da oun duro sibẹ.

Ni bayii, EFCC ti tule kan awọn aṣiri nla kan, wọn lawọn n ṣewadii bi owo ti iye rẹ le lọgọrin biliọnu owo dọla ($80.2b) to poora mọ Yahaya Bello lọwọ nigba to n ṣejọba Kogi. Gbogbo igbiyanju EFCC lati fi pampẹ ofin gbe ọkunrin naa ni ko ti i seeso rere latari bo ṣe yọ pọrọ mọ wọn lọwọ, latigba naa lo si ti lọọ fara ṣoko sibi kan, ko yọju sita, ko si jọwọ ara rẹ fun iwadii titi di ba a ṣẹ n sọ yii.

Leave a Reply