Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Ile-ẹjọ Majsitreeti kan to wa niluu Ado-Ekiti ti paṣẹ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, pe ki ọmọ ogun ọdun kan, Oluwapẹlumi Alọ, maa lọọ gbatẹgun lọgba ẹwọn titi di igba kan na.
Ọmọkunrin to n kọ iṣẹ mẹkaniiki niluu Iyin-Ekiti lawọn ọlọpaa gbe wa si kootu lori ẹsun igbimọ-pọ lati paayan.
Agbefọba, Insipẹkitọ Bamikọle Ọlasunkanmi, ṣalaye niwaju adajọ pe Oluwapẹlumi ṣẹ ẹṣẹ naa lọjọ kẹrinlelogun, oṣu keje, ọdun yii, niluu Iyin-Ekiti, nijọba ibilẹ Irẹpọdun/Ifẹlodun, nipinlẹ Ekiti.
Agbefọba yii sọ pe ọdaran naa atawọn kan ti ọlọpaa ṣi n wa bayii ni wọn gbimọ-po, ti wọn si pa ọkunrin kan to n ta awó tutu niluu naa ti orukọ rẹ n jẹ Jafaru Mohammed.
O ṣalaye pe lọjọ ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ, ija kekere kan lo waye laarin Oluwapẹlumi ati oloogbe naa, ti ọdaran yii si gbe okuta nla kan, to la a mọ oloogbe naa lori, eleyi to pada ja si iku fun un.
Ẹsẹ yii ni agbefọba naa juwe gẹgẹ bii oun to lodi sofin 516 to jẹ ofin iwa ọdaran tipinle Ekiti n lo, ti wọn kọ ni ọdun 2012.
Agbefọba naa waa tọrọ aaye ranpẹ lọwọ ile-ẹjọ naa pe ki oun le raaye fi iwe ẹsun naa ṣọwọ si ajọ to n gba ile-ẹjọ nimọran (DPP), fun imọran ati ki oun le ri aaye ko awọn ẹlẹrii oun jọ.
O ṣeleri pe oun ṣetan lati ko awọn ẹlẹrii mẹta wa si ile-ẹjọ naa, ṣugbọn aaye ranpẹ yii ni oun yoo fi ṣa awọn ẹlẹrii oun jọ lati fara han ni kootu naa.
Onidaajọ Abduhamid Lawal sọ pe ki ọdaran ọhun maa lọ si ọgba ẹwọn fun igba kan na, o si sun igbẹjọ si ọjọ kẹtalelogun, oṣu kẹsan-an, odun 2021.