Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Obinrin kan torukọ ẹ n jẹ Ọlamide Akinwalere, foju ba kootu Majisreeti Ọta l’ Ọjọruu to kọja yii, nitori wọn lo pe ara ẹ ni sajẹnti ọlọpaa ni olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa l’Abẹokuta, bẹẹ, ki i ṣe agbofinro nibi kankan.
Agbefọba E.O Adaraloye, ṣalaye pe Ọlamide to n jẹjọ yii lọọ fẹjọ kan sun ni teṣan ọlọpaa ni, lo ba si debẹ, lo ni ọlọpaa loun naa, ati pe olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa l’Abẹokuta loun ti n ṣiṣẹ.
Obinrin naa sọ eyi lati ri ojuure awọn ọlọpaa to n fẹjọ sun ni, ki wọn si le fi ọwọ tiwa-n-tiwa mu ẹjọ oun debii pe iya gidi yoo jẹ awọn to waa fi ẹjọ wọn sun.
Ṣugbọn iwadii fi han pe puruntu lasan ni olujẹjọ naa gẹgẹ bi agbefọba ṣe wi, ohun to si ṣe yii lodi si abala irinwo ati mẹrinlelọgọrin ( 484) iwe ofin iwa ọdaran ti ipinlẹ Ogun n lo, eyi ti wọn ṣe lọdun 2006.
Nigba to n ṣalaye ara ẹ, Ọlamide ti ile-ẹjọ ko sọ pato ibi to n gbe, sọ pe oun ko jẹbi rara.
Bo ṣe loun ko jẹbi naa lo jẹ ki Adajọ Abilekọ A.O Adeyẹmi faaye beeli silẹ fun un pẹlu ẹgbẹrun lọna ogun naira pẹlu oniduuro meji niye kan naa.
Awọn oniduuro naa gbọdọ niṣẹ gidi lọwọ gẹgẹ b’adajọ ṣe wi, wọn gbọdọ maa gbe nitosi kootu, wọn si gbọdọ ni iwe-ẹri owo-ori sisan funjọba ipinlẹ Ogun.
Igbẹjọ mi-in di ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kejila yii.