Ọlayẹmi n digunjale, o tun n ṣẹgbẹ okukun l’Ọwọ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ile-ẹjọ Majisireeti kin-in-ni to wa l’Oke-Ẹda, niluu Akurẹ, ti ni ki okunrin ẹni ọdun mẹtadinlogoji kan, Oluṣọla Ọlayẹmi, ṣi wa lọgba ẹwọn na lori ẹsun idigunjale ti wọn fi kan an.

Ọlayẹmi, ẹni ti inagijẹ rẹ n jẹ Don Para, lawọn ẹṣọ alaabo ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ gbe wa si kootu lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja lori ẹsun idigunjale, fifi iya jẹ ni lọna aitọ ati ẹgbẹ okunkun ṣíṣe.

ALAROYE gbọ pe olujẹjọ ọhun atawọn mi-in tawọn ọlọpaa ṣi n wa ni wọn fẹsun kan pe wọn fiya jẹ ọmọbinrin kan, Kẹmisọla Aarẹ, lọna aitọ, ti wọn si tun ja ẹnikan ti wọn porukọ rẹ ni Oluwaṣeun Adeyinka lole X5 iphone, niluu Ọwọ, ninu oṣu Kọkanla, ọdun to kọja.

Bakan naa ni wọn tun fẹsun kan an pe o tun lọwọ ninu ẹgbẹ okunkun ṣiṣe laarin ọdun 2020 si 2022, bo tilẹ jẹ pe o ti kọkọ figba kan kede pe oun ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ okunkun mọ.

Ọjọ kẹrinla, oṣu Kejila, ọdun to kọja, lọwọ awọn ṣọja tẹ Don Para lagbegbe Gareeji Ado to wa niluu Ọwọ, ti wọn si fa a le awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ lọwọ fun igbesẹ to yẹ.

Awọn ẹsun mẹtẹẹta ti wọn fi kan olujẹjọ ọhun ni Agbẹnusọ fun ijọba, Amofin D. T. Akinmuwagun, ni o ta ko abala ọta-le-lọọọdunrun (360), ọkanlenirinwo (401) ati ejilenirinwo (402) nínú iwe ofin ipinlẹ Ondo ti ọdun 2006.

Olujẹjọ ni oun ko jẹbi eyikeyii ninu awọn ẹsun naa.

Akinmuwagun waa rọ ile-ẹjọ lati paṣẹ pe ki wọn fi ọkunrin naa pamọ ṣọgba ẹwọn titi ti imọran yoo fi wa lati ọfiisi ajọ to n gba adajọ nimọran.

Nigba to n gbe ipinnu rẹ kalẹ, Onidaajọ Musa Al-Yunnus, gba ẹbẹ agbefọba wọle pẹlu bo ṣe ni ki olujẹjọ ọhun ṣi lọọ maa gbatẹgun l’ọgbà ẹwọn Olokuta, titi di ogunjọ, oṣu Kẹrin, ọdun yii ti igbẹjọ yoo tun maa tẹsiwaju.

Leave a Reply