Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ọmọkunrin kan, Sodiq Adegoke, ati ọrẹ rẹ, Opẹyẹmi Abubakar, lọwọ ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti tẹ lori ẹsun igbo tita ati gbigba owo lọna aitọ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, ṣalaye pe lẹyin ti awọn afurasi mejeeji ko akẹkọọ kan, Usu Joseph, ni papamọra, ti wọn si gba ẹgbẹrun lọna aadọjọ Naira lọwọ rẹ ni ọwọ tẹ wọn.
Ọpalọla ṣalaye pe ṣe ni wọn mu Joseph lọ sibi kan niluu Oṣogbo, ti wọn si sọ pe ko ṣe tiransifaa owo naa si akanti awọn.
Ṣugbọn nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ, Sodiq ṣalaye pe iṣẹ telọ loun kọ, ṣugbọn airiṣẹ-ṣe lo sun oun dedii iwa ti oun n hu.
O ni loootọ lawọn gba owo lọwọ Joseph, ṣugbọn awọn ko fi agidi gba a lọwọ ẹ, nitori iṣẹ Yahoo to n ṣe lo jẹ kawọn ba a sọrọ, ti awọn si fi gbowo naa.
Sodiq sọ siwaju pe agbegbe Dada Estate, niluu Oṣogbo, lawọn ti ri Joseph to n gun ọkada lọ, o ni nigba ti awọn da a duro lawọn ri i pe ọmọ Yahoo ni.
O ni bi awọn ṣe mu un lọ si ibi kan lọna GRA, niluu Oṣogbo niyẹn. “Nigba ti a yẹ ori foonu rẹ wo, mo ri alaati ẹgbẹrun mọkanlelaaadọta (51,000) kan, mo si tun ri ẹgbẹrun lọna ojilenigba o le kan (241,000) kan, igba yẹn lo sọ fun wa pe ki i ṣe oun loun ni ẹgbẹrun lmọkanlelaaadọta yẹn.
“Ninu ẹgbẹrun lọna ojilenigba o le kan (241,000) to jẹ tiẹ, o bẹ wa pe ka gba ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un Naira, ṣugbọn mo sọ fun un pe ẹgbẹrun lọna aadọjọ Naira la maa n gba, o si ṣe tiransifaa rẹ sinu akanti Abubakar.
“A ti gba ẹgbẹrun lọna marundinlaaadọrun ninu owo naa ki wọn too mu wa, ki i ṣe pe a fi tipatipa mu un, oun lo fun wa.”
Ọpalọla ṣalaye pe awọn mejeeji yoo kawọ pọnyin rojọ ni kootu ni kete tiwadii ba ti pari.