Ole meji gbadajọ iku n’Ibadan, wọn dana sun ọkan, ọkada pa ekeji nibi to ti n sa lọ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Lati ile aye nibi lawọn ole meji kan ti gba idajọ wọn ki wọn too lọọ jiya yooku lọdọ Olodumare lode ọrun pẹlu bi awọn mejeeji ṣe lasidẹnti, ti awọn eeyan si dana sun ọkan ninu wọn lẹyin ti ọkan ti padanu ẹmi ẹ ninu ijanba ori ọkada naa.

Awọn ole ti ẹnikẹni ko da mọ tabi mọ orukọ wọn yii ni wọn ja foonu gba mọ ọkunrin kan to n jẹ Tobi Adebayọ lọwọ ni nnkan bii aago mẹta aabọ ọsan Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii laduugbo Favors, ni Bodija, n’Ibadan.

Bi wọn ṣe n sa lọ, ti ọkunrin onifoonu naa atawọn ẹlẹyinju aanu si n le wọn lọ lọkada wọn ti gbokiti nitosi sẹkiteriati ijọba ipinlẹ Ọyọ, l’Agodi, n’Ibadan.

ALAROYE gbọ pe nibi ti wọn ṣubu si naa lọkan ninu wọn gba kọja lọ sọrun aṣante.

Nibi ti ẹni keji ti n japoro iku lọwọ lawọn eeyan ti ya bo o, kia ni wọn sọ taya si i lọrun ti wọn tu epo bẹntiroolu si i lara, ti wọn si dana sun un pa si oju titi nibẹ.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, SP Olugbenga Fadeyi, fidi ẹ mulẹ, awọn agbofinro ti palẹ oku awọn ole mejeeji ọhun mọ, wọn si ti gbe wọn lọ si ile igbokuu-si Adeọyọ, iyẹn ileewosan ijọba ipinlẹ Ọyọ to wa n’Ibadan.

 

Leave a Reply