Ole mẹtala tun ko sakolo ọlọpaa l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

 

 

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Hakeem Odumosu, ti fọwọ sọya bayii pe gbogbo ọna yoowu kawọn ole gba, gbogbo ọgbọn yoowu ti wọn le da, awọn maa ri i pe pampẹ ofin gbe wọn, wọn si jiya ẹṣẹ wọn loju paali, afi ti wọn ba jawọ.

Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii lọga ọlọpaa naa sọrọ idaniloju ọhun lọfiisi rẹ nigba to n ṣafihan awọn afurasi mẹtala kan tọwọ awọn agbofinro ṣẹṣẹ ba, wọn fẹsun kan wọn pe igaara ọlọṣa ni wọn, wọn ni nibi ti wọn n ja awọn ero ati onimọto lole lawọn ọna marosẹ Eko kan ni wọn ti mu wọn.

Hakeem Ridwan, ẹni ọdun mejilelogun, lọjọ-ori ẹ kere ju ninu awọn a-lọ-kolohun-kigbe ẹda yii, nigba ti Onyeka Muogbara, ẹni ogoji ọdun joye agbaaya aarin wọn.

Lara wọn ni Emmanuel Anthony, ẹni ọdun mẹrinlelogun, Sikiru Ọlanrewaju, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn, Favour Elijah, ẹni ọdun mẹrindinlọgbọn, Silas Manner, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn ati Oriyọmi Ṣolọla, ẹni ọdun mejidinlọgbọn.

Orukọ awọn to ku Kayọde Dele, ẹni ọdun mọkanlelọgbọn, Muhammadu Aminu ati Riliwan Salaudeen tawọn mejeeji jẹ ẹni ọdun mejilelọgbọn, Taiwo Akeredọla ati Joseph Ovie jẹ ẹni mẹtalelọgbọn, Monday Nweke, ẹni ọdun marundinlogoji loun.

Alukoro ọlọpaa Eko, Olumuyiwa Adejọbi, ṣalaye f’ALAROYE pe ikọ ọlọpaa ayara-bii-aṣa RRS lo mu awọn afurasi ọdaran naa, nibi ti wọn lugọ si lagbegbe Too-geeti atijọ, nitosi ileeṣẹ 7-Up, n’Ikẹja, ni wọn ti mu awọn kan lara wọn. Ibi tawọn kan ti n fa igbo ati awọn egboogi oloro lọwọ nitosi akitan Oluọsun to wa l’Ọjọta, lo ni wọn ti ko awọn yooku.

Ṣa, ọdọ awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ni Panti, Yaba, lawọn afurasi yii ti maa lọọ ṣalaye ẹnu wọn gẹgẹ bi Kọmiṣanna Odumosu ṣe paṣẹ. O ni ti iwadii ba ti pari, ilẹ-ẹjọ lọrọ wọn n lọ.

Leave a Reply