Adajọ agba nipinlẹ Ogun, Abilekọ Mosunmọla Dipẹolu, ti jẹ ko di mimọ pe ole wọ ọfiisi oun, nibi tawọn ẹrọ tawọn fi n ṣe ẹjọ lori ayelujara wa, wọn si ji awọn eelo naa lọ.
Ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu kọkanla yii, ni Adajọ Dipẹolu sọ eyi di mimọ lasiko ti wọn n ṣefilọlẹ ọna igbalode ti wọn yoo fi maa jokoo ṣẹjọ lori ayelujara lai jẹ pe wọn wa ni kootu ( Digitisation of judicial process).
Dipẹolu ṣalaye pe lasiko ti Korona gbilẹ gidi lọdun to kọja, ti kootu ko le ṣilẹkun, ni eto gbigbọ ẹjọ lori ayelujara naa bẹrẹ diẹdiẹ, tawọn n lo awọn nnkan irinṣẹ igbalode lati gbe idajọ kalẹ lai jẹ pe ẹjọ n pẹ nilẹ.
O ni ṣugbọn lasiko kan, awọn ole wọ ọfiisi oun, wọn si ko awọn nnkan ẹrọ tawọn n lo fi ṣeto naa lọ, eyi si mu ifasẹyin ba iṣẹ igbẹjọ lori ayelujara nipinlẹ yii.
Bo tilẹ jẹ pe adajọ agba ko ṣalaye ju bayii lọ lori ẹrọ to ni wọn ji lọ yii, obinrin naa sọ pe ko le rọrun lati ṣiṣẹ lori ayelujara bi ẹka idajọ ko ba da wa laaye ara wọn bawọn ṣe n beere fun un, iyẹn ‘Judicial autonomy’
“Latigba tawọn ole ti wọ ọfiisi mi ti wọn ji awọn irinṣẹ tijọba ṣe sibẹ lọ, ẹrọ alaagbeka kọmputa temi ni mo n lo lati fi gbẹjọ lori ayelujara. Eto to daa ni gbigbọ ẹjọ lori ayelujara, o maa n muṣẹ ya, o si maa n jẹ keeyan tete ni anfaani sawọn ẹjọ to ba wa niwaju ẹ.”