Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta
Bi ẹ ṣe n ka iroyin yii, ko si ọpa aṣẹ agbara mọ nile igbimọ awọn aṣofin ipinlẹ Ogun, awọn ole ti gba abẹ orule wọ ọfiisi abẹnugan ibẹ, wọn si ti gbe ọpa naa lọ
Ọjọbọ, ọsẹ yii, ti i ṣe ọjọ kẹwaa, oṣu kejila, ọdun yii niṣẹlẹ yii ṣẹlẹ, nigba ti awọn ole kan wọ ọgba ile-igbimọ naa to wa l’Oke-Mosan, l’Abẹokuta.
Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, tilẹ ti fidi ẹ mulẹ pẹlu, pe awọn kan ti gbe ọpa ti wọn n pe ni Mace lede oyinbo naa lọ.
Bo tilẹ jẹ pe wọn ti ri abala ọpa naa ti wọn ya ami asia orilẹ-ede yii si, apa keji rẹ to jẹ ọpa gan-an ko ti i jẹ riri, wọn ṣi n wa a lasiko ta a pari iroyin yii ni.
Alukoro ọlọpaa sọ pe awọn ko ti i mu ẹnikẹni gẹgẹ bii afurasi lori iṣẹlẹ yii, o ni ṣugbọn iwadii ṣi n tẹsiwaju, awọn yoo si mu awọn to wa nidii ọpa aṣẹ ti wọn gbe lọ naa.
Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ lori iṣẹlẹ yii, Ọlakunle Oluọmọ, olori ile naa, sọ pe oun ko fura si ẹnikẹni. O ni oun ri ohun to ṣẹlẹ naa bii ole jija, awọn ọlọpaa ni yoo tuṣu desalẹ ikoko, ti wọn yoo si fi oju awọn aṣebi naa han.
Nipa bo ṣe jẹ dandan ki ọpa yii wa ninu ile lasiko ti wọn ba n jokoo ipade nile naa, Oluọmọ ni bo ṣe sọnu yii ko ni kawọn ma jokoo ipade. O ni to ba to asiko fawọn lati jokoo, ọpa aṣẹ yoo jade.