Njẹ ẹyin gbọ nipa ọmọbinrin kan ti wọn lo gun baba alaaanu ẹ pa laipẹ yii? Iyẹn ni Uyo, nipinlẹ Akwa Ibom.
Awọn to mọ obinrin naa ti sọrọ, wọn ni Lauretta lo n jẹ, ko si niṣẹ meji ju iṣẹ aṣẹwo lọ. Wọn ni oloṣo gidi ni Lauretta, bo ṣe gun Chukuemeka pa ko jẹ nnkan kan loju oloṣo ọlọdun pipẹ bii tiẹ rara.
Ṣe iroyin to gun ori ayelujara l’Ọjọbọ, ọjọ karun-un, oṣu kẹjọ yii, ni pe ọkunrin kan tun ti riku ojiji he lọwọ ọrẹbinrin rẹ o, bii eyi to ṣẹlẹ laipẹ yii l’Ekoo, ti Chidinma Ojukwu gun baba olowo ti wọn jọ n fẹra wọn pa.
Ohun ti a gbọ nipa ti Lauretta yii ni pe o pẹ ti ọkunrin to gun pa yii ti n gbe e jade, ti wọn jọ n ṣere ifẹ, ti ọkunrin oniṣowo nla naa si n ṣaye fun ọmọbinrin yii daadaa.
Ṣugbọn ko jọ pe owo ti Lauretta n ri gba lọwọ Chukuwemeka to o, niṣe lo si gbero lati kuku pa a patapata, ko si jogun rẹ lai jẹ pe ẹnikẹni mọ bo ṣe ṣẹlẹ.
Afi bo ṣe di lọsẹ to kọja yii ti wọn ṣere oge tan ti ọkunrin oniṣowo naa si sun lori bẹẹdi, ti Lauretta si gun un pa sibẹ lai ro o lẹẹmeji rara.
A gbọ pe bo ti gun un tan lo kowo to to miliọnu meje nile ọkunrin naa, bakan naa lo si gbe mọto rẹ ti wọn pe ni Benz 4matic, o gbe mọto ọhun toun ti gbogbo ojulowo iwe rẹ ni, n lo ba sa lọ tefetefe.
Awọn ọrẹ oloogbe ti wọn jọ n ṣowo reti rẹ titi pe ko waa yanju ọja rẹ to de lati oke okun, wọn ko ri i, wọn pe e, ko gbe ipe rẹ, ni wọn ba kuku wa a lọ sibi to n gbe. Nigba ti wọn debẹ ni wọn ba oku Chukuemeka ninu agbara ẹjẹ, pẹlu oju apa ibi ti wọn ti gun un pa.
Wọn fi to ọlọpaa leti, iwadii si bẹrẹ, bẹẹ ni wọn fi irinṣẹ ti wọn fi n mọ ibi ti mọto ti wọn ji gbe ba wọle si, wa ọkọ ti Lauretta gbe lọ.
Lẹyin naa ni wọn ka a mọ ileetura kan to ti n ṣe faaji, wọn ni bo ti n jẹ lo n mu, to si n ṣe faaji ara ẹ gidi lẹyin ọjọ diẹ to pa baba alaaanu rẹ tan, bi wọn ṣe mu un ṣinkun niyẹn.
Ọmọbinrin yii ti paarọ gbogbo orukọ Chukuemeka kuro lori iwe mọto naa, o ti fi tiẹ si i, ko maa lo o lọ lai si wahala loun ro, ko mọ pe oloogbe ti ṣe ohun ti wọn yoo fi tọpasẹ ọkọ naa debikibi si i lara.
Wọn ni ọlọpaa ni Baba Lauretta, ati pe Ogoja, nipinlẹ Cross River, ni baba rẹ ti n gbe ofin ro, ọmọ rẹ to gbe ofin ṣanlẹ ni Akwa Ibom naa si ti wa ni teṣan ọlọpaa Ewet, ni Uyo.