Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ajọ panapana tipinlẹ Kwara lo pada yọ gende-kunrin kan ti ko sẹni to mọ orukọ rẹ jade ninu odo Asa, to wa ni Emir’s Road, Ilọrin, ipinlẹ Kwara.
Iroyin to tẹ ALAROYE lọwọ ni pe ni nnkan bii aago meji ọsan ọjọ Aje, Monde, ọṣẹ yii, ni ọkunrin kan torukọ rẹ n jẹ Olamilekan ri oku arakunrin ọhun labẹ biriiji odo Asa to wa ni agbegbe Ẹmir’s Road, niluu Ilọrin, ti wọn ti de e lokun lọwọ sẹyin. O ke si ajọ panapana, ni wọn ba yọ oku ọkunrin naa jade ninu odo, wọn ri i pe wọn so o lọwọ sẹyin, wọn si tun fi nnkan bo o lẹnu.
Agbẹnusọ ajọ panapana nipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Hakeem Adekunle, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni awọn ti gbe oku naa lọ si olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa niluu Ilọrin fun ẹkunrẹrẹ iwadii.
Ọga agba ajọ panapana nipinlẹ Kwara, Ọmọọba Falade John Olumuyiwa, rọ gbogbo awọn araalu lati maa kiyesara ninu igbokegbodo wọn lojoojumọ lati denu iru iṣẹlẹ abami bayii.
Titi ta a fi pari akojọpọ iroyin naa, wọn ko ti i ri ẹnikankan gba mu lori iṣẹlẹ naa.