Faith Adebọla, Eko
Titi di asiko yii lawọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ṣi n wa Ifeanyi Nwagboroga, latari ẹsun pe o gun iyawo ẹ, Faith Ebubeeze, l’ọbẹ pa l’Oṣodi.
Alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Olumuyiwa Adejọbi, ṣalaye pe ni nnkan bii aago mọkanla alẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, to kọja yii, niṣẹlẹ naa waye nile tawọn ololufẹ mejeeji yii n gbe l’Opopona Adekunle, l’Oṣodi, nipinlẹ Eko. Ṣọọbu aṣọ kan ni wọn ni oloogbe naa ti n taja lọja igbalode Arena Market.
Adejọbi ni iwadii tawọn ṣe fi han pe awọn mejeeji yii ti jọ n gbe papọ bii tọkọ-taya lati nnkan bii ọdun mẹta sẹyin, bo tilẹ jẹ pe wọn o ti i ṣegbeyawo, ọrọ bi wọn ṣe maa ṣegbeyawo naa ni wọn lo dija silẹ, ko too dogun a n yọbẹ sira ẹni.
Lọjọ tọrọ yii ṣẹlẹ, wọn ni ariyanjiyan nla kan waye laarin awọn mejeeji, Faith ni bawọn ṣe jọ n gbe latọdun yii lai ṣegbeyawo ti su oun, ko jẹ kawọn lọọ so yigi bo ṣe yẹ, ṣugbọn ọkunrin naa loun ko ti i ṣetan, ko fun oun laaye diẹ si i, ati pe oun loun maa pinnu igba to maa jẹ toun ba ti rẹdi (ready).
Ọrọ yii ni wọn lo bi oloogbe naa ninu, lo ba sọ fọkọ ẹ pe to ba jẹ ohun to fẹẹ ṣe niyẹn, a jẹ pe ajọsẹ oun atiẹ maa dopin, oun o le duro mọ ni toun, tori naa kawọn pin gaari. Wọn lọkunrin naa ba loun maa gba ẹgbẹrun lọna irinwo naira, owo toun na fun un laipẹ yii lọwọ ẹ koun too le yọnda ẹ, lọrọ ba di pe awọn mejeeji n jagbe mọ ara wọn, tawọn alajọọgbele wọn si n gbọ ohun fatafata, ṣugbọn ko sẹni to ba wọn da si i.
Wọn ni niṣe lafurasi ọdaran naa kọja si kiṣinni wọn, o fa ọbẹ yọ, o si gun ọmọbinrin naa pa. Ẹyin to gun un tan ni wọn lo palẹkun de, o jade bii ẹni fẹẹ lọọ mu nnkan nisalẹ, lo ba fere ge e, o si salọ rau.
Ko pẹ lẹyin eyi lawọn eeyan gbọ bọmọbinrin naa ṣe n pọkaka iku, ni wọn ba yọju sibẹ, wọn ba a to ti rakoro de bakoni (balcony) ile naa, ẹjẹ si wa nilẹ rẹpẹtẹ, wọn tun ba aṣọ ti afurasi naa fi di i lẹnu pinpin, ni wọn ba tu aṣọ kuro, wọn si sare gbe e lọ sọsibitu boya wọn aa ṣi le doola ẹmi ẹ, ṣugbọn ẹpa ko boro mọ, oloogbe naa ti dakẹ ki wọn too de’bẹ.
Awọn aladuugbo ni wọn lọọ fọrọ ọhun to ileeṣẹ ọlọpaa leti ni teṣan Akinpẹlu, l’Oṣodi. Adejọbi ni awọn ti gbe oku obinrin naa lọ fun ayẹwo, ikọ ọtẹlẹmuyẹ si ti bẹrẹ si i wa afurasi ọdaran naa kaakiri, o lawọn ko ti i ri, ṣugbọn o daju pe ẹgbẹrun saamu ẹ ko le sa mọ Ọlọrun lọwọ.