Faith Adebọla, Eko
Ohun ti ikọ adigunjale kan to n yọ awọn onimọto lẹnu lagbegbe Morogbo, loju ọna Badagry, nipinlẹ Eko, reti kọ ni wọn ba pẹlu bi ọkan lara awọn igaara ọlọṣa naa ṣe dagbere faye, tawọn yooku si fẹsẹ fẹ ẹ nigba tawọn ọlọpaa ṣina bolẹ fun wọn.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, ni nnkan bii aago mẹta ọsan Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii niṣẹlẹ naa waye.
Wọn lawọn adigunjale naa lo kọkọ yinbọn fun ọlọpaa kọburu ti wọn porukọ ẹ ni Patrick, nibi to ti n fi ọkada ẹ ṣe patiroolu loju ọna ọhun, ibọn naa ṣe ọlọpaa yii leṣe lẹsẹ, ni wọn ba gbe ọkada ẹ sa lọ.
Ṣugbọn ko pẹ tawọn ọlọpaa teṣan Morogbo fi gbọ nipa iṣẹlẹ yii, ni wọn ba tọpasẹ awọn adigunjale naa, wọn si le wọn ba.
Ninu atẹjade kan ti Olumuyiwa Adejọbi, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, fi sọwọ s’ALAROYE nipa iṣẹlẹ naa, o ni niṣe lawọn adigunjale ọhun doju ibọn kọ awọn ọlọpaa bi wọn ṣe foju ri mọto wọn, lawọn naa da a pada fun wọn.
Ninu iṣẹlẹ yii nibọn ti ba ọkan lara awọn adigunjale ọhun oju ẹsẹ lo si ti dagbere faye, wọn lọkunrin naa ko ti i le ju ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn lọ.
Ibọn ponpo kan, ọpọlọpọ ọta ibọn, oogun abẹnu-gọngọ lawọn ọlọpaa ri gba pada, bẹẹ ni wọn tun gba ọkada ọlọpaa kọburu tawọn ole naa gbe sa lọ.
Olumuyiwa ni gbogbo isapa lawọn ọlọpaa ati ẹka ọtẹlẹmuyẹ ti n ṣe lati wa awọn adigunjale naa ri, ki wọn si fiya to tọ jẹ wọn labẹ ofin.
Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko naa fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o si parọwa fawọn araalu lati tubọ maa ta ileeṣẹ ọlọpaa lolobo ti wọn ba ti kẹẹfin awọn kolọransi ẹda wọnyi laduugbo wọn.