Ọlọpaa ati Fulani kan ku lasiko tawọn agbebọn fẹẹ ji oyinbo gbe l’Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

O kere tan, awọn afurasi Fulani mẹrin lọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti tẹ bayii latari wahala kan to ṣẹlẹ nigba ti awọn agbebọn fẹẹ ji awọn oyinbo meji gbe niluu Ifẹwara, nipinlẹ Ọṣun.

Ninu iṣẹlẹ naa ni Insipẹkitọ ọlọpaa kan ti padanu ẹmi rẹ, nigba ti Fulani agbebọn kan naa tun padanu ẹmi rẹ.

Awọn ọlọpaa naa la gbọ pe wọn n ṣọ awọn oyinbo meji ti wọn n ṣiṣẹ nibudo iwakusa kan labule Aruwa, niluu Ifẹwara, nipinlẹ Ọṣun.

Ṣugbọn laaarọ ọjọ Aiku, Sannde, to kọja, la gbọ pe awọn ajinigbe naa da mọto wọn lọna, ti wọn si dana ibọn bolẹ, nibẹ ni ibọn ti ba ọlọpaa naa.

Ọlọpaa keji toun jẹ sajẹnti ṣọkan akin, o doju ibọn kọ awọn agbebọn naa, ọkan lara wọn si ku sibẹ.

Awọn agbebọn yii gbe ibọn Inspẹkitọ ti wọn pa lọ, bẹẹ ni awọn ọlọpaa naa gba ibọn ọwọ Fulani to ku, pẹlu ọta-ibọn ati foonu meji.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni aago meje idaji Sannde lo waye.

Gẹgẹ bo ṣe wi, bi awọn ọlọpaa agbegbe naa ṣe gbọ ni wọn ti sare debẹ, ti wọn si fọn sinu igbo, nibẹ ni ọwọ ti tẹ awọn afurasi Fulani mẹrin.

Leave a Reply