Ọlawale Ajao, Ibadan
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ ipaniyan to waye lọna Mọniya, n’Ibadan, ninu eyi ti awọn amookunṣika ẹda ti pa eeyan mẹta ọtọọtọ lẹẹkan naa, ti wọn si gbe oku wọn ju sẹgbẹẹ titi.
Laaarọ kutu ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kejila yii, lawọn olugbe adugbo ibudokọ kan ti wọn n pe ni Ọfiisi, nitosi ileepo World Oil, to wa lọna Ọjọọ si Mọniya, n’Ibadan, pẹlu awọn arinrin-ajo to gba ibudokọ naa kọja deede ba oku gende eeyan mẹta ọhun nilẹẹlẹ nibẹ.
Iṣẹ ọwọ awọn apaniṣeyutu lawọn eeyan ro iṣẹlẹ yii si nitori niṣe ni wọn fi ada ati ọbẹ dara si awọn eeyan naa lara lẹyin ti wọn pa wọn tan.
Ko ti i sẹni to da awọn oku ọhun mọ, bẹẹ lẹnikẹni ko ti i mẹni to pa wọn titi taa fi pari akojọ iroyin yii.
Awọn araadugbo ọhun ti wọn ri awọn oku mẹtẹẹta fidi ẹ mulẹ pe ọkunrin lawọn mẹtẹẹta, wọn si ti fi ada ge ori ọkan ninu ọdọkunrin naa lọ, nigba ti wọn ge nnkan ọmọkunrin awọn meji yooku.
Agbofinro ti palẹ awọn oku naa mọ kuro nibẹ laaarọ ọjọ keji, iyẹn lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.
Nigba to n fidi iroyin yii mulẹ, Alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, SP Adewale Ọṣifẹṣọ, sọ pe “A ti palẹ awọn oku yẹn mọ kuro nibẹ nitori oorun to maa bẹrẹ si i da pa awọn araadugbo yẹn, ati lati dena ajakalẹ arun to ṣee ṣe kí iru nnkan bẹẹ da silẹ lawujọ.
“Iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ yii, a o si maa fi gbogbo bo ba ṣe jẹ to gbogbo aye leti ni kete ti iwadii ta a n ṣe ba ti seeso rere”.