Ọlọpaa bẹrẹ iwadii lori Ẹgbẹ Akẹkọọ Poli Offa to fun awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun lami-ẹyẹ

Stephen Ajagbe, Ilorin

Iwadii ti bẹrẹ bayii lori iroyin kan to gba ori ẹrọ ayelujara pe ẹgbẹ akẹkọọ, SUG, tileewe Poli Ọffa fun awọn ẹgbẹ okunkun ni ami-ẹyẹ laipẹ yii.

Laarin ọsẹ yii ni aworan awọn ami-ẹyẹ naa ti wọn kọ orukọ awọn ẹgbẹ okunkun mẹta ọtọọtọ si lori gba ori ẹrọ ayelujara. Latigba naa lawọn eeyan si ti n sọ ọrọ buruku lu ẹgbẹ akẹkọọ ọhun, paapaa ju lọ Abiọla Azeez Adigun to jẹ Aarẹ ẹgbẹ naa.

ALAROYE gbọ pe kete ti kinni ọhun ta si Ọga ọlọpaa nipinlẹ Kwara, Kayọde Ẹgbẹtokun, leti lo ti ni ki ẹka to n ṣewadii iwa ọdaran, CID, lọọ ṣewadii rẹ kiakia.

Bakan naa la tun gbọ pe awọn alaṣẹ ileewe ọhun ko kawọ gbera lori iṣẹlẹ naa, wọn ti gbe igbimọ oluwadii kan dide lati mọ boya loootọ lọrọ naa ri bẹẹ tabi ko ri bẹẹ.

Ninu aworan to n kaakiri ọhun lori ikanni ‘Twitter’ gbagada lorukọ ẹgbẹ akẹkọọ Poli Ọffa wa lori awọn ami-ẹyẹ naa pẹlu orukọ ẹgbẹ okunkun Alora, Aye, ati Ẹiyẹ.

Ṣugbọn, Abiọla Azeez Adigun ti ni ẹgbẹ SUG ko fun ẹgbẹ okunkun lami-ẹyẹ kankan o. O ni awọn ko mọ ibi ti ami-ẹyẹ ti wọn n gbe kiri naa ti wa, nitori pe ki i ṣe lati ọdọ awọn. O ni o ṣee ṣe ko jẹ pe awọn eeyan kan lo lọọ fi kọmputa ṣe kinni ọhun jade lati ba awọn lorukọ jẹ.

Tẹ o ba gbagbe, lọdun 2018 lọwọ ọlọpaa tẹ Igbakeji aarẹ ẹgbẹ akẹkọọ Poli Ọffa, Tajudeen Selim, ẹni ti wọn fẹsun kan pe o n ṣe ẹgbẹ okunkun.

Capt: Awon ami-eye naa

Leave a Reply