Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Inu ọfọ nla ni awọn mọlẹbi Ọlọfa ti ilu Ọfatẹdo, nijọba ibilẹ Ẹgbẹdọrẹ, nipinlẹ Ọṣun, wa bayii, latari bi awọn kan tawọn eeyan fura si bii ọmọ ẹgbẹ okunkun ṣe yinbọn pa ọkan lara awọn ọmọ baba naa.
Yinusa Abdullahi, ẹni ọdun mẹtalelogoji, la gbọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọn jẹ mẹta yii lọọ ba nile laago mejila oru ọjọ Ẹti, Furaidee, mọju Satide, ti wọn si darukọ ẹnikan to da mọ pe o n beere rẹ, bo ṣe silẹkun lati wo ẹni naa ni wọn dana ibọn fun un nigbaaya, to si ku patapata.
Iwadii ALAROYE fi han pe akinkanju ni Yinusa, o si jẹ ẹni ti ko fẹ iyanjẹ rara. A gbọ pe lalẹ ọjọ Furaidee lo ba awọn ọdọkunrin naa nibi ti wọn ti n fa wahala pẹlu baba onikorope kan latari pe wọn ko fẹẹ sanwo fun baba naa.
O da si ọrọ yii, o si kilọ fun awọn ọdọkunrin naa gẹgẹ bo ṣe maa n ṣe, pe ki wọn dẹkun iwa to le ba orukọ ilu Ọfatẹdo jẹ, ki wọn si ki ọwọ ọmọ wọn bọṣọ. Latibẹ la gbọ pe wọn ti ni ikunsinu pẹlu ọmọọba yii, ko too di pe wọn lọọ pa a sile rẹ loru.
Iṣẹlẹ naa da wahala silẹ niluu laaarọ ọjọ Abamẹta, Satide, tori ṣe lawọn ọdọ fọn sita, ti wọn ko si jẹ ki awọn onimọto raaye kọja ko too di pe awọn agbaagba ilu atawọn ọlọpaa parọwa si wọn lati fun awọn agbofinro laaye lati ṣiṣẹ ọwọ wọn.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni laago kan aabọ oru ni Ismail Azeez to n gbe lagbegbe Ọlọfa, niluu Ọfatẹdo, lọ si agọ ọlọpaa to wa niluu naa, to si fi to wọn leti pe awọn afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun mẹta lọ sile Yinusa, wọn si yinbọn fun un.
Ọpalọla sọ siwaju pe wọn ti gbe oku ọmọọba yii lọ sile igbokuu-si ti ọsibitu UNIOSUN, niluu Oṣogbo, iwadii si ti bẹrẹ lati ri awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti wọn huwa naa mu nibikibi ti wọn ba sa si.