Faith Adebọla, Eko
Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, CP Hakeem Odumosu ti ṣalaye pe ẹtọ gbogbo ọmọ Naijiria ni iwọde jẹ, tori naa awọn ko ni i gbegi dina fun ẹnikẹni to ba fẹẹ ṣewọde alaafia, titi kan iwọde EndSARS tawọn kan n gbero rẹ.
Odumosu sọrọ yii lọjọ Aiku, Sannde, nigba to n ba awọn oniroyin kan sọrọ lori bi iṣẹ aabo nibi eto idibo abẹle awọn ẹgbẹ oṣelu meji, APC ati PDP, ṣe lọ si nipinlẹ Eko.
O ni ojuṣe awọn ọlọpaa ni lati daabo bo awọn oluwọde, ki wọn si ri i pe awọn janduku ko ja iwọde naa gba mọ wọn lọwọ, tabi huwa ọdaran, bẹẹ ni iwọde naa ko gbọdọ ṣediwọ fun lilọ bibọ ọkọ nipinlẹ Eko.
Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa (NAN), ṣalaye pe ọga ọlọpaa Eko naa sọ pe oun fẹ kawọn oluwọde ati awọn ọlọpaa jọ fọwọ sowọ pọ, ki wọn si gbọ ara wọn ye ni.
“Tẹ ẹ ba fẹẹ ṣewọde, ẹtọ yin ni labẹ ofin, ṣugbọn ẹ o ni lati dina mọ awọn to n rinna tori tẹ ẹ ba ṣe bẹẹ, ẹ tun ti n fi iwọde naa fa inira fawọn mi-in niyẹn, iyẹn o si le mu kaye daa.
Ki lo maa ṣẹlẹ sawọn alaboyun to n rọbi, tabi ti ile ba da wo lojiji, tabi tawọn oṣiṣẹ panapana gba ipe pajawiri nigba ti awọn oluwọde ba ti dina mọ lilọ bibọ ọkọ?
A o gbọdọ gbagbe pe Eko yatọ ninu gbogbo ilu, ojuko rọ-aje orileede yii ni, ọjọ iṣẹ si lọjọ ti wọn fẹẹ ṣewọde yii, awọn eeyan gbọdọ lọ sẹnu iṣẹ ounjẹ oojọ wọn. Awọn eeyan kan wa ti wọn o ni i le de ibi ti wọn ti n ṣe ka-ra-ka-ta wọn nigba ti ọna ba di pa.”
Odumosu waa gba awọn ọdọ to gun le ṣiṣe iwọde EndSARS naa lamọran pe ki wọn ma ṣe jẹ ki iwọde naa fa laasigbo mi-in nipinlẹ Eko.
Ṣaaju nileeṣẹ ọlọpaa ti kọkọ tẹ atẹjade kan lọsẹ to kọja pe awọn ko ni i yọnda fẹnikẹni lati fi iwọde da omi alaafia ilu Eko ru, tori naa, awọn o ni i faaye gba ṣiṣe iwọde logunjọ, oṣu kẹwaa, bawọn kan ṣe n gbero rẹ.
Ọrọ yii ti da awuyewuye nla silẹ pẹlu bawọn ọdọ atawọn agbalagba mi-in ṣe n kilọ fawọn ọlọpaa pe ẹtọ araalu ni lati fẹhonu han tabi ṣe iwọde.
Ogunjọ, oṣu kẹwaa yii, ni awọn ọdọ to fẹẹ ṣewọde naa fi eto wọn si, wọn lawọn fẹẹ fi ayajọ naa ṣeranti ohun to ṣẹlẹ lasiko iwọde ta ko awọn ọlọpaa SARS tijọba fofin de lọdun to kọja latari iwọde naa.