Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ti fẹsun ijinigbe kan awọn mẹta kan ti wọn jọ Fulani, tawọn eeyan si fura si bii darandaran. Awọn afurasi naa ni Sabiu Yusuf, Barga Mohammadu ati Bello Abubakar.
Gẹgẹ bi Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Ekiti, Sunday Abutu, ṣe ṣalaye, ni nnkan bii aago kan aabọ ọsan ọjọ kẹsan-an, oṣu yii, ni ikọ ọlọpaa mu awọn mẹtẹẹta ninu igbo kan to wa laarin Ikẹrẹ-Ekiti si Igbara Odo-Ekiti.
O ni awọn eeyan kan lo ta ikọ naa lolobo ti wọn fi gbe igbesẹ ọhun, nigba tọwọ si tẹ Sabiu, Barga ati Bello, wọn ko ri alaye gidi kankan ṣe lori idi ti wọn fi wa ninu igbo naa.
Awọn nnkan ti Abutu sọ pe wọn ba lọwọ awọn eeyan naa ni ọkada Bajaj, Maggi, iyọ, epo pupa ati oogun abẹnugọngọ, eyi to jọ pe wọn fẹẹ lọọ ko fawọn kan ninu igbo kijikiji ọhun.
Abutu ni awọn eeyan naa gbọdọ jẹjọ iwa ti wọn hu nitori gbogbo ẹri to wa nilẹ fi han pe ọwọ wọn ko mọ, wọn si n ṣiṣẹ ibi pẹlu awọn kan tọwọ ko ti i tẹ.
Alukoro naa waa ni ko saaye fawọn ajinigbe ati ọdaran l’Ekiti, nitori ojoojumọ nileeṣẹ ọlọpaa n gbiyanju lati ṣeto aabo to nitumọ.