Ọlọpaa ti mu Adekunle to kọwe pe oun fẹẹ waa ji awọn akẹkọọ fasiti kan gbe l’Ọyọọ

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ọkan ninu awọn afurasi ajinigbe to n fooro ẹmi awọn eeyan lagbegbe Ọyọ, Ọlarinde Adekunle, ti ko si panpẹ awọn ọlọpaa ipinlẹ naa.

Adekunle yii lo kọ lẹta si awọn alaṣẹ ileewe fasiti aladaani kan niluu Ọyọ, lọjọ kẹjọ, oṣu Kẹjọ, ọdun 2022 yii, pe oun n bọ waa ji awọn akẹkọọ wọn bii meloo kan gbe, ṣugbọn bi wọn ko ba fẹ bẹẹ, ki wọn lọọ wa miliọnu lọna ọgọrun-un Naira wa.

Bẹẹ naa lo lẹ iwe mọ iwaju ileefowopamọ kan nigboro ilu Ọyọ, o ni wọn ku imurasilẹ fun agbako ati idaamu, nitori oun pẹlu awọn ọmoogun oun n ko ibọn nla nla bọ waa ja wọn lole, ọ pẹ tan, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹjọ, ti i ṣe ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii. Ṣugbọn bi wọn ba fẹẹ sa fun ofo ẹmi ati adanu ọkẹ aimọye miliọnu Naira to ṣee ṣe ki idigunjale naa mu wa, ki wọn pe oun, ki oun rọra gba miliọnu lọna ọgọrun-un Naira lọwọ wọn wọọrọwọ, o kuku ti kọ nọmba ẹrọ ibanisọrọ ti wọn le pe e si sinu lẹta ọhun.

Ṣugbọn bi ọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlogoji (37) yii ṣe n ronu ọna lati pa awọn ileeṣẹ mejeeji naa lẹkun jaye, bẹẹ lawọn agbofinro n dọdẹ rẹ kaakiri bii igba ti ologinni n dọdẹ ekute. Nigba ti oun yoo si fi ṣeto ijanba to n gbero lati ṣe yii, ọwọ awọn ọlọpaa ya ju tiẹ lọ, alakọri ko ti i ri ijanba kankan ṣe fawọn to kọwe ijaya sí ti wọn fi gba a mu ṣinkun.

Nigba to n fi ọkunrin afurasi ọdaran yii han awọn oniroyin lolu ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ to wa laduugbo Ẹlẹyẹle, n’Ibadan, ọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CP Adebọwale Willams, sọ pe ọwọ ni jagunlabi fi kọ lẹta naa si awọn ileeṣẹ mejeeji, to si kọ nọnba ti wọn le pe e si naa sibẹ.

“Lẹyin tọwọ tẹ ẹ tan ni iwadii wa fidi ẹ pe ọkunrin kan to n jẹ Azeez Mufutau lo ni nọmba ẹrọ ibanisọrọ ti wọn fi sinu awọn lẹta naa”, bẹẹ ni CP William sọ.

Azeez ṣọ pe oun ko mọ nnkan kan nipa ẹsun ijinigbe ati idigunjale ti wọn fi kan oun. Amọ ṣa, Adekunle ti jẹwọ pe oun loun mọn-ọn-mọ-ọ lo nọmba foonu Azeez  sinu lẹta naa ki ẹnikẹni ma baa le mọ pe oun loun wa nidii iwa ọdaran naa nigbakuugba ti aṣiri ba tu.

Adekunle ti wa latimọle awọn ọlọpaa l’Ẹlẹyẹle, n’Ibadan, bayii. CP Williams si ti n mura lati pe e lẹjọ si kootu, ko le jiya to ba tọ si i labẹ ofin

 

 

Leave a Reply