Jide Alabi
Bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa ko ti i sọ ohunkohun lori iku ojiji ti ọlọpaa kan to n tẹle Olori ile igbimọ aṣoju-aṣofin, Fẹmi Gbajabiamila, fi pa fẹndọ kan niluu Abuja, sibẹ, ẹgbẹ awọn fẹndọ ti sọ pe ọlọpaa yii gan-an lo pa a.
Lọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, iyẹn lasiko ti olori ile-igbimọ aṣoju-ṣofin ọhun n kọja lagbegbe Sẹkiteria ijọba apapọ, niluu Abuja, ni deede aago mẹta ọsan ni Ifeanyi Okereke pade iku ojiji ọhun, nigba ti ọlọpaa tọ n ṣọ Fẹmi Gbajabiamila binu yinbọn fun un lori.
Wọn ni awọn fẹndọ ko ṣẹṣẹ maa pe bo mọto awọn eeyan nla nla ti wọn ba ti kọja lati taja fun wọn, iru ẹ gan-an lo ṣẹlẹ l’Ọjọbọ yii, ki iku ojiji too pa ọkan ninu wọn.
ALAROYE gbọ pe bi wọn ṣe ri mọto olori ile-igbimọ yii ni wọn ti bo o, ti oun naa si fun wọn lowo gẹgẹ bii iṣe ẹ, ṣugbọn ṣadeede ni ibọn dun, bi ọkan ninu awọn fẹndọ ọhun ṣe ba ara ẹ nilẹẹlẹ niyẹn, ti ẹjẹ si bo o loju ẹsẹ.
National Hospital ni wọn sare gbe e lọ, nibẹ naa ni wọn ti sọ pe o ti ku.
Alaga awọn fẹndọ lagbegbe Etim Eteng, niluu Abuja, sọ pe wọn ko ṣẹṣẹ maa sare tẹle awọn eeyan nla nla ti wọn ba ti kọja, koda, wọn mọ awọn nọmba mọto wọn lori daadaa. Alaga yii fi kun un pe ohun to ṣẹlẹ lọjọ naa niyẹn ki ọlọpaa to n ṣọ Gbajabiamila yii too yinbọn fun Ifeanyi lori, to si ti dero ọrun bayii.
Gbajabiamila sọ pe loootọ niṣẹlẹ naa waye, ati pe o ba oun ninu jẹ gidigidi. O ni, “Ko sigba ti mo kọja ti mi o ki i duro ki wọn, ipo ti wọn wa yẹn gan-an lo maa n mu mi duro, ti ma a si mu inu wọn dun, bi ọkan ninu awọn ẹṣọ mi ṣe yinbọn pa ọkan ninu wọn yii ba mi ninu jẹ pupọ. Bẹẹ ni mi o le sọ iru ipo ti awọn mọlẹbi Ifeanyi maa wa bayii. Mo ba wọn kẹdun, bakan naa ni mo ba awọn ẹlẹgbẹ ẹ naa kẹdun paapaa.”
Agbenusọ fun National Hospital, Dr Tayọ Haastrup, ti sọ pe loootọ lọkunrin naa ti ku, ibọn ti wọn yin fun un lori lo si pa a.