Olori ileegbimọ aṣofin agba ni ki Buhari yọ awọn ọga ologun nipo

Olori ile-igbimọ aṣofin agba, Ahmed Lawan, ti ke si Aarẹ Muhammadu Buhari lati yọ awọn olori ẹṣọ ologun ni kiakia, ko si fi awọn mi-in rọpo wọn, nitori bi eto aabo ṣe ri lorilẹ-ede Naijiria bayii.

Bi awọn janduku afẹmi-ṣofo ṣe pa awọn agbẹ mẹtalelogoji nipinlẹ Borno lo mu olori awọn aṣọfin ke si Buhari lati tete gbe igbesẹ ọhun.

O ni ki Buhari gbiyanju lati ṣatunto si eto aabo orilẹ-ede yii, ki eto aabo to peye le wa fun awọn eeyan Naijiria ati dukia wọn.

Lawan sọ pe, “Mo fẹẹ fi asiko yii ke si Aarẹ orilẹ-ede Naijiria ko paarọ awọn lọgaa-lọgaa lẹnu iṣẹ ologun, ko si fi awọn mi-in rọpo wọn, ati pe pupọ ninu awọn ti wọn jẹ ọga yii paapaa ni wọn ti pẹ ju bo ṣe yẹ lọ, bẹẹ lo yẹ ki a ni awọn mi-in ti wọn yoo fi oye gidi ṣiṣẹ sin Naijiria, paapaa lori eto aabo.

“Asiko niyi fun Aarẹ lati ṣeto bi atunṣe ati atunto yoo ṣe ba eto aabo orilẹ-ede yii, bakan naa ni ijọba tun gbọdọ pese awọn irinṣẹ to yẹ lati fi koju awọn janduku a-fẹmi-ṣofo to n da Naijiria atawọn eeyan ẹ laamu.”

Siwaju si i, Lawan ti rọ ịjọba apapọ ko gbe igbimọ kan kalẹ ti yoo ṣewadii lori ẹsun oriṣiriiṣi ti wọn fi n kan awọn to wa nidii eto aabo lori iwa ajẹbanu.

 

Leave a Reply