Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Oluwoo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi, ti sọ pe ṣe loun gbọ ohun latọdọ Ọlọrun pe ki oun fi gbajugbaja oniroyin nni, Oloye Dele Mọmọdu, jẹ oye Aarẹ.
Kabiesi sọ pe ninu ọgba Fasiti Bowen loun ti gba idari naa lati ọdọ Ọlọrun lọdun mẹta sẹyin, nigba ti oun ṣalabapade Dele Mọmọdu.
Nigba to n jawe oye Aarẹ le Dele Mọmọdu atiyawo rẹ to fi jẹ Yeye Aarẹ lori lagbala aafin lọjọ Abamẹta, Satide, ni Ọba Adewale sọrọ yii.
O ni oun maa n bọwọ fun ohunkohun ti Ọlọrun ba sọ fun oun. O ṣalaye pe bi Ọlọrun ṣe ba oun sọrọ nipa oloye tuntun naa fi han pe eeyan Ọlọrun ni, aṣẹ Ọlọrun yii lo si jẹ ki oun fi oye naa da a lọla lai gba ṣiṣi lọwọ ẹ.
Oluwoo ṣapejuwe Dele Mọmọdu gẹgẹ bii ẹni to ko ara rẹ nijaanu, to si n gbe igbe-aye ọwọ. O ni lẹnu iwọnba asiko perete ti oun ti kede ọrọ oye yii, oniruuru ipa rere lawọn araalu yii n ri.
Bakan naa lo rọ ọ lati lo anfaani oye naa fun idagbasoke ilẹ Iwo, o ni bo tilẹ jẹ pe oloye tuntun yii ti fi da oun loju pe gbogbo erongba oun nipa titun Iwo sọ bii ẹni sọgba yoo wa simuṣẹ, sibẹ, oun rọ ọ lati ma ṣe kaaarẹ lori rẹ rara.