Olowo lawọn eeyan n pe Alaaji Ramọni ni Kwara, aṣe ajinigbe ni, ọpọlọpọ owo ni wọn ka mọ ọn  lọwọ

Faith Adebọla

Okoowo jiji eeyan gbe ni ọkunrin kan ti wọn porukọ ẹ ni Alaaji Rahmọni mu bii iṣẹ, ọpọ eeyan lo si ti pa lẹkun pẹlu bo ṣe n gbowo gọbọi lọwọ awọn mọlẹbi ẹni toun atawọn ẹmẹwa ẹ ba ji gbe, ṣugbọn ọwọ ti ba jagunlabi l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.

Agbegbe Odo-Ọwa, nijọba ibilẹ Okeero, nipinlẹ Kwara, la gbọ pe awọn ọdọ kan ti wọn ti n dọdẹ awọn oniṣẹ laabi ọhun ti lọọ ka Rahmọni mọ, ibi to ti n reti ati gbowo itusilẹ miliọnu mẹfa lọwọ awọn mọlẹbi to ji eeyan wọn kan gbe sahaamọ rẹ, ibẹ lọwọ palaba wọn ti segi, ti wọn fi ri wọn mu.

A gbọ pe iṣẹ jijinigbe ti wọ ọkunrin naa lẹwu debii pe titi wọnu asiko aawẹ tawọn Musulumi wa lo fi n ba iṣẹ buruku rẹ lọ, wọn ni nnkan bii ọjọ meji ṣaaju asiko yii lo gba miliọnu meji naira lọwọ awọn kan ko too tu eeyan wọn to ji gbe silẹ.

Nigba tawọn ọdọ naa mu un, wọn wọ ọ tuurutu de ile to loun n gbe, wọn si ba ọpọ miliọnu naira owo to pa nidii okoowo buruku to n ṣe ọhun ninu yara rẹ.

Wọn nipari oṣu Disẹmba to kọja lafurasi ọdaran yii ṣẹṣẹ ra ọkọ olowo nla jiipu kan, wọn ni miliọnu mẹẹẹdogun naira lo ra ọkọ afẹ ọhun, lara owo to pa nidii iṣẹ jijinigbe lo fi ra a.

Ohun ta a ri gbọ ni pe ọpọ igba lọkunrin naa maa n dibọn bii pe darandaran kan ni, o maa n mura bii awọn Fulani darandaran, ṣugbọn iṣẹ buruku lo kun ọwọ rẹ.

Wọn tun loun lo ni otẹẹli kan to wa niluu Omu-Aran, nipinlẹ Kwara. Awọn ọdọ tinu n bi ọhun ti lọọ dana sun otẹẹli ati ile to n gbe lẹyin ti wọn ti gbọn gbogbo agbala ile naa yẹbẹ.

Wọn ni wọn ti fa afurasi ọdaran yii ati akẹgbẹ rẹ kan tọwọ ba le awọn ṣọja lọwọ fun igbesẹ to yẹ labẹ ofin.

 

Leave a Reply