Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ọba Adekunle Makama Oyelude, Tẹgbosun Kẹta, ti i ṣe Olowu ti ilu Kuta, nipinlẹ Ọṣun, ti rawọ ẹbẹ si ijọba apapọ orileede yii lati wa ojutuu si ọrọ iyanṣẹlodi ti awọn olukọ fasiti gun le lati nnkan bii oṣu meje bayii.
Nigba ti Ọba Makama pade agbarijọpọ ẹgbẹ awọn akẹkọọ fasiti ilẹ wa, NANS, nibi ti wọn ti n fẹhonu han lori iyanṣẹlodi ọlọjọ gbọọrọ naa loju ọna marosẹ Eko si Ibadan lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii lo parowa naa.
Kabiesi, ẹni to sọkalẹ pẹlu awọn ọba alaye ti wọn jọ kọwọọrin lati ba awọn akẹkọọ naa sọrọ, bẹ wọn lati ṣi awọn agbegbe ti wọn di lojupopo naa, ki awọn arinrin-ajo le raaye kọja.
O fi da wọn loju pe oun yoo patẹ ọrọ naa siwaju awọn alaṣẹ lai fi falẹ rara. Ọba Adekunle tun gboṣuba fun awọn ọdọ naa pẹlu bi wọn ṣe bu ọla fun un, bẹẹ lo gboroyin fun awọn agbofinro fun bi wọn ṣe ri i pe ifẹhonu han wọọrọwọ naa ko yọri si wahala.
O waa ke si ijọba lati daabo bo awọn ọjọ-ọla orileede yii, ki wọn ma baa di ohun eelo ayalo lati da orileede yii ru. Ki wọn wa gbogbo ọna lati yanju wahala iyanṣẹlodi naa kiakia.