Faith Adebọla
Ero pitimu lo ya bo aafin Olubadan tilẹ Ibadan, eyi to wa lagbegbe Popo-Yemọja, niluu Ibadan, l’Ọjọruu, Wẹsidee yii, nigba tawọn araalu atawọn ololufẹ ajijagbara ilẹ Yoruba nni, Oloye Sunday Adeyẹmọ, lọọ fẹhonu han lọdọ Ọba Saliu Adetunji, lori akọlu tawọn agbofinro ṣe sile Sunday Igboho lọsẹ to kọja.
Lati ile Sunday Igboho to wa lagbegbe Sọka, n’Ibadan, lawọn ọdọ naa ti gbera, wọn gbe akọle ‘Oduduwa Nation’ dani, pẹlu awọn akọle mi-in ti wọn fi bẹnu atẹ lu iṣẹlẹ to waye loru Ọjọbọ, nile Sunday Igboho, bẹẹ ni wọn n pariwo “Igboho, Ooṣa,” “Oodua Nation la fẹ,” “A o ni i jawọ, a o ni i sinmi,” bi wọn ṣe n lọ.
Lara ohun tawọn eeyan naa n beere pe ki Olubadan ba awọn da si ni bijọba ṣe mu awọn mẹtala lati ile Sunday Igboho sahaamọ awọn otẹlẹmuyẹ DSS l’Abuja, bi wọn ṣe ba dukia wọn jẹ, ti wọn fo gilaasi ọkọ to wa lagbala Sunday Igboho, ati awọn dukia mi-in ti wọn ko lọ.
Awọn eeyan naa tun beere pe kijọba ṣalaye idi ti wọn fi ṣeku pa eeyan meji nile Sunday Igboho lọjọ ti wọn wa, ati titẹ ti wọn tẹ ẹtọ Adeyẹmọ loju.
Ọkan lara awọn ọdọ naa to ṣoju fawọn to ku sọrọ laafin Olubadan, o ni:
“A fẹẹ sọ fawọn ẹṣọ DSS pe ki wọn fagi le ikede ti wọn ṣe pawọn n wa Oloye Sunday Adeyẹmọ, ati pawọn fẹẹ fi pampẹ ofin gbe e nibikibi tawọn ba ti ri i. Gbedeke ọjọ meje la fun wọn lati ṣe eyi.
A tun fẹ ki idajọ ododo waye lori awọn oṣiṣẹ Sunday Igboho meji ti wọn yinbọn pa, awọn mejeeji ọhun, Adogan ati Aafaa (inagijẹ wọn) lawọn DSS ṣekupa laiṣẹ lairo loru ọjọ ti wọn ṣakọlu ọhun.
A si fẹ kijọba da awọn mẹtala ti wọn mu sahaamọ wọn l’Abuja, a fẹ ki wọn fi wọn silẹ laarin ọjọ meje pere.
Ọjọ meje la fun ijọba lati dahun awọn ibeere wa yii, a si n ṣoju fun gbogbo ọmọ Yoruba to ju ọgọta miliọnu lọ kari aye. Tijọba ba kọti ikun si ibeere yii, a ti ṣetan lati gbe pẹrẹgi kana pẹlu wọn. Ti DSS ba le mu gbogbo ọgọta miliọnu ọmọ Yoruba, a ṣetan lati woran wọn. Awa o bẹru DSS kankan o, ohun ta a fẹ la n pariwo ẹ seti ijọba yii.
“Lẹyin iwọde yii, a maa bẹrẹ si i lọ kaakiri gbogbo aafin awọn ọba alaye ilẹ Yoruba lọkọọkan lati sọ erongba wa ati ibeere wa fun wọn.”
Lẹyin to ti tẹti bẹlẹjẹ si wọn tan, ọkan ninu awọn ijoye laafin Olubadan lo fesi lorukọ Kabiyesi ọhun, o ni, “Sunday Igboho ki i ṣajoji si Olubadan rara. Ọba ti gbọ gbogbo ibeere yin, wọn si maa ṣiṣẹ lori ẹ lai sọsẹ. Wọn maa pe awọn ori ade to ku sipade lati jiroro ọrọ yii, didun lọsan yoo si so lori ẹ.
Lẹyin naa ni Olubadan funra ẹ ṣadura fawọn ọdọ naa, o si rọ wọn pe ki wọn ṣewọde wọn wọọrọwọ, ki wọn ma ṣe jẹ kawọn janduku fi iwọde naa kẹwọ lati da yanpọnyanrin silẹ.
Bakan naa ni Oluranlọwọ Olubadan feto iroyin, Ọgbẹni Adeọla Ọlọkọ, lo anfaani naa lati ṣalaye pe rumọọsi lasan lọrọ to n lọ nigboro ati lori ẹrọ ayelujara pe Olubadan gba ogun miliọnu naira lọwọ ijọba lati le jẹ ki wọn ri Sunday Igboho mu, o lọrọ naa ki i ṣe ootọ rara.
O ni ọmọ Olubadan ni Sunday Igboho, gbogbo igba loun ati Kabiyesi si maa n sọrọ lori erongba rẹ fun ilẹ Yoruba.