Jọkẹ Amọri
Nitori awọn iwa aṣemaṣe ti wọn ni o n ṣe, Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba Saliu Akanmu Adetunji, ti rọ ọkan ninu awọn baalẹ to wa labẹ iṣakoso rẹ, Saidi Alatishe, Baalẹ Lagelu Abọke, to wa ni ijọba ibilẹ Ido, nipinlẹ Ọyọ loye o.
Gẹgẹ bi atẹjade ti Akọwe iroyin Olubadan, Adeọla Ọlọkọ, fi sita, o ni ọkunrin naa ti n luwẹẹ ninu wahala kan ati omi-in latigba to ti di baalẹ ninu oṣu kẹsan-an, ọdun 2017.
O fi kun un pe ọpo igba ni wọn ti n mu ẹsun baalẹ naa wa fun awọn iwa ko tọ to n hu kaakiri, eyi ti wọn lo lodi si aṣa ati ofin ilẹ Ibadan. Wọn ni laarin ọdun kan ti wọn fi n fi ẹsun kan ọkunrin yii, niṣe lo tun kọ lati waa sọ awijare tirẹ nigba ti wọn pe e pe ko waa ṣe bẹẹ. Eyi to jẹ iwa arifin si Olubadan ati awọn igbimọ rẹ.
Lara ẹsun to ni wọn fi kan an ni pe o pe ara rẹ ni ohun ti ko jẹ pẹlu bo ṣe fẹẹ fi awọn kan joye, nigba ti ko lẹtọọ lati ṣe bẹẹ nitori ki i ṣe ọmọ ọkunrin ninu idile naa.
Ninu lẹta ti awọn mọlẹbi Lagelu Abọke kọ si igbimọ Olubadan, eyi ti olori ẹbi wọn, Ganiyu Oladokun Okerinu Abọke, ati akọwe wọn kọ ni wọn ti sọ pe Saidi Alatiṣe to wa lati mọlẹbi Agbẹdẹ Adodo, n’Ibadan, ko le jẹ aṣoju fun mọlẹbi Lagelu Abọke ti Idi-Iṣhin, Bẹẹrẹ, niluu Ibadan.
Wọn ni yatọ si eleyii, awọn ko fọwọ si iwa ati iṣe rẹ, nitori iwa rẹ gẹgẹ bii baalẹ yatọ si awọn imọran ti wọn maa n fun awọn baalẹ ko too di pe wọn fi wọn joye baalẹ.
Eyi lo ni o fa a ti awọn igbimọ Olubadan fi fẹnu ko lati rọ ọkunrin naa loye. Irọloye yii si bẹrẹ loju-ẹsẹ ni.