Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ọnarebu Ṣọla Arabambi, to jẹ oludije funpo ileegbimọ aṣofin-ṣofin latinu ẹgbẹ oṣelu PDP lati ẹkun Irewọle/Iṣọkan/Ayedaade, nipinlẹ Ọṣun, ni wọn ti kede iku rẹ bayii.
Arabambi, ẹni to jẹ ọmọ bibi ilu Apomu, la gbọ pe o jade laye lẹyin aisan ranpẹ, ti wọn si ti gbe oku rẹ sile igbokuu-si kan to wa niluu Oṣogbo.
Ọkunrin oloṣelu yii ni ẹgbẹ oṣelu PDP dibo yan lasiko idibo abẹle wọn lati koju Ọnọrebu Taiwo Oluga, ti ẹgbẹ APC to ti wa nileegbimọ lati ọdun 2019.
Ko sẹni to ti i le sọ pato aian to ṣe e tọlọjọ fi de. Ọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ni wọn ti n sọ nipa iku ọkunrin naa, ti wọn si n ba awọn mọlẹbi oloogbe daro iku ojiji to mu ọkunrin naa lọ lasiko to n gbiyanju lati ran awọn eeyan agbegbe rẹ lọwọ, iyẹn to ba jẹ pe iku ko pa oju rẹ de, ti wọn si fibo gbe e wọle.