Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Bo tilẹ jẹ pe wọn ko ti i kede fun gbogbo ilu, ALAROYE fidi rẹ mulẹ pe Olufọn ti Ifọn, Ọba Almoroof Adekunle Magbagbeọla, ti waja.
Laaarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, la gbọ pe baba naa waja. Ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu karun-un, ọdun 2007, ni baba naa gori itẹ awọn baba-nla rẹ.
Ileeṣẹ ifọpo NNPC to wa ni Warri ni baba naa ti ṣiṣẹ ko too di ọba.
Iwadii fi han pe wọn ti fi iku kabiyesi to Gomina Oyetọla leti, oniruuru eto ti bẹrẹ lati gba “ooṣa” ọwọ ori-ade naa ki wọn to kede fun gbogbo ilu.