Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Lẹyin to lo ọdun marundinlogoji lori itẹ awọn baba nla rẹ, Olukoyi ti Ikoyi, nijọba ibilẹ Iṣọkan, nipinlẹ Ọṣun, Ọba Yisau Bamitalẹ Oyetunji Ọtunla, Kodaolu 1, ti waja.
Alaroye gbọ pe baba yii jade laye lẹyin aisan ranpẹ. Ọdun 1987 ni baba naa gori itẹ.
Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni wọn yoo feeru fun eeru ninu aafin Olukoyi.
Alaga ijọba ibilẹ agbegbe Guusu Iṣọkan, Ọmọọba Wasiu Oyetunji Oyelami, ṣapejuwe kabiesi naa gẹgẹ bii ẹni ti asiko rẹ mu idagbasoke ba ilu Ikoyi.