Ọwọ ọlọpaa tẹ marun-un lara awọn to da wahala ẹgbẹ awakọ ati onikẹkẹ Maruwa silẹ n’llọrin

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
O kere tan, eeyan marun-un lọwọ tẹ lara awọn to fa rogbodiyan to waye laarin ẹgbẹ awakọ NURTW ati ẹgbẹ onikẹkẹ Maruwa TOAN, niluu Ilọrin, lopin ọsẹ to lọ yii.
ALAROYE gbọ pe ọrọ ti ko to nnkan lo da rogbodiyan silẹ laarin onikẹkẹ Maruwa ati baba kan to n wa ọkọ Mitsubishi, lagbegbe Okoolowo, ti ija ọhun si di ija igboro. Ọpọ lo fara pa yannayanna, wọn ba kẹkẹ Maruwa to le ni ogun jẹ, ti ko ṣe e tunṣe mọ, bẹẹ ni ibẹru bojo gbalẹ lọkan awọn to n gbe ni agbegbe Okoolowo, Ogidi, Ọlọjẹ, Ọmọda, titi de ọja ọba, nitori pe gbogbo agbegbe yii ni wọn ti n fi ada ati kumọ le ara wọn kiri, ti wọn si n wọ agboole si agboole lọọ ba gbogbo kẹkẹ Maruwa ti wọn ba ri jẹ. Ọjọ mẹta gbako ni wọn fi fa wahala yii, tawọn ẹgbẹ onimọto si yari pe kẹkẹ Maruwa kankan ko gbọdọ na Okoolowo si ọja mọ.
Ni bayii, Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Ọkasanmi Ajayi, ni afurasi marun-un lọwọ ti tẹ, ti wọn si ti n ṣẹju peu ni galagala awọn latari pe wọn n da omi laaafia ilu ru.
O tẹsiwaju pe Kọmisanna ọlọpaa nipinlẹ Kwara, Tuesday Assayomo, ti ikilọ fawọn adari ẹgbẹ ohun lati fa awọn ọmọ ẹgbẹ wọn leti, ki wọn yee da omi alaafia ilu ru, tori gbogbo awọn tọwọ ba tẹ ni wọn yoo fimu kata ofin ijọba.

Leave a Reply