Minisita ere idaraya tẹlẹ, Solomon Dalung, kuro lẹgbẹ APC

Faith Adebọla
Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), tun ti padanu ọkan ninu awọn alẹnulọrọ wọn, Minisita fun ere idaraya ati ọrọ awọn ọdọ nilẹ wa tẹlẹ, Ọgbẹni Solomon Dalung, o loun ko ba ẹgbẹ naa lọ mọ.
Dalung sọ ipinnu rẹ yii di mimọ ninu lẹta kan to kọ si alaga ẹgbẹ APC ni Wọọdu SabonGida, ijọba ibilẹ Langtang, nipinlẹ Plateau.
Lẹta to buwọ lu funra ẹ ọhun lọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹrin yii, ka lapa kan pe:
“Eyi ni lati sọ fun yin pe mi o ṣe ọmọ ẹgbẹ APC mọ, bẹrẹ lati deeti to wa loke lẹta yii.
“Mo ti ṣakiyesi pe awọn nnkan to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ oṣelu naa lẹnu lọọlọọ yii ko ba erongba ati iwa mi mu, wọn ta ko ara wọn, mi o si le fara mọ ọn.
“Mo ti ri i pe ko si eto ati ẹtọ lori ilana ti wọn fi n dari ẹgbẹ naa labẹnu, ko si daju pe bi nnkan ṣe n lọ yii, ẹgbẹ naa yoo le ṣoju fawọn araalu bo ṣe yẹ labẹ ijọba awa-ara-wa, tori ẹ ni mo ṣe pinnu lati pọ soke raja.”
Bẹẹ ni minisita to ṣejọba fọdun mẹrin saa akọkọ Aarẹ Buhari yii sọ.
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ Aiku, Sannde, to kọja yii, ni gomina ana nipinlẹ Zamfara, Abdulaziz Yari, ati Sẹnetọ Marafa binu da ẹgbẹ Onigbalẹ naa nu, wọn lawọn o ba wọn ṣe mọ, wọn si ti fẹẹ bọ sinu ẹgbẹ PDP, bi alaga ẹgbẹ naa ṣe sọ.

Leave a Reply