Ibrahim Alagunmu, Ilorin
Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrasaq, ti gbe ọpa asẹ fun Olupo ti ilu Ajasẹ-Ipo tuntun, Ọba Ismail Yahaya Atọloye Alebiosu, gẹgẹ bii ọba onipo kin-in-ni nipinlẹ Kwara.
Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ yii, ni Abdulrasaq gbe ọpa asẹ fun Ọba Alebiosu ni ilu Ajasẹ-Ipo, nijọba ibilẹ Irẹpọdun, nipinlẹ Kwara, lẹyin ọjọ kẹta ti wọn buwọ lu iyansipo ori ade ọhun.
Gomina waa ki Olupo tuntun ọhun ku oriire, pẹlu bo ṣe jẹ pe oun ni aayo awọn araalu, ti wọn si fi tayọtayọ gba a gẹgẹ bii ọba wọn.
Bakan naa gomina tun gboriyin fawọn ọmọ bibi ilu naa fun bi wọn ṣe gba alaafia laaye lasiko iyansipo ọba tuntun. Ko sai juwọ kare sawọn igbimọ afọbajẹ ilu naa, fun bi wọn ṣe ṣeto iyansipo Ọba Alebiosu ni irọwọrọsẹ.
Abdulrasaq waa pe gbogbo awọn ọba alaye nipinlẹ Kwara lati maa da awọn eeyan wọn lẹkọọ, lati jẹ ọmọ orilẹ-ede rere, nipa gbigba alaafia ati iṣọkan laaye nigba gbogbo.
Kọmisanna fun ijọba ibilẹ to n ri si ọrọ awọn lọba lọba nipinlẹ Kwara, Aliyu Saifuddeen, parọwa si ọba tuntun ọhun pe ko lo anfaani ipo rẹ lati mu iṣọkan, alaafia ati idagbasoke ba ilu to n jọba le lori, ko ma si ja awọn eeyan rẹ kulẹ.
Ọba tuntun yii waa dupẹ lọwọ tolori tẹlẹmu niluu Ajasẹ-Ipo, fun iduroti wọn, paapaa ju lọ gomina ipinlẹ Kwara, fun ifọwọsi yiyan ti wọn yan an sipo, o ṣeleri pe oun yoo mu ayipada rere ba ilu Ajasẹ-Ipo ati gbogbo agbegbe rẹ.