Oluwo ṣọtun sosi, ko ba ibi kan jẹ, eyi lawọn orukọ to sọ ọmọ rẹ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Oluwoo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi, ti sọ ọmọbinrin tuntun tiyawo rẹ, Olori Firdaus, ṣẹṣẹ bi fun un ni orukọ. Orukọ ọmọ naa lo sọ ni iranti Ọlọfin Adimula ti Ile-Ifẹ, to n jẹ Luwo Gbagida.

Luwo Gbagida yii ni wọn pe ni ọmọbinrin kan ṣoṣo  to jẹ Ọlọfin Adimula Ileefẹ, to si tun jẹ iya Adekọla Telu to da ilẹ Iwo silẹ.

O ṣapejuwe Luwo Gbagida yii bii akikanju, onigboya eeyan, to si tun jẹ ọba obinrin akọkọ ni gbogbo agbaye.

Ninu atẹjade to fi sita nipasẹ Akọwe iroyin rẹ, Ali Ibrahim, lo ti sọ pe ‘‘Mo n fi itan balẹ lonii pẹlu bi mo ṣe ṣọ ọmọ mi lorukọ ni iranti obinrin alagbara nni, iya wa, Luwo Gbagida.

Luwo Gbagida nikan ni obinrin to jẹ Ọlọfin Adimula n’Ileefẹ. Awọn ipa ti ko ṣee fọwọ rọ sẹyin to la kalẹ ati igboya rẹ lo bi ilu Iwo. O waa fi ade rẹ fun ọmọ ọkunrin kan ṣoṣo to bi, Adekọla Telu, lati da ilu oloooto, ilu Ayekootọ, ilu Iwo, silẹ.’’

Bi kabiesi se fun ọmọ naa ni orukọ Musulumi, lo fun un ni ti Kirisitẹni, to si fun un ni ti Yoruba.

Lasiko ayẹyẹ isọmọlorukọ naa to ṣe funra rẹ ninu eyi ti awọn ọba alaye, awọn aṣaaju ẹsin, awọn aṣaaju ilu atawọn afẹnifẹre wa, eyi to waye laafin rẹ niluu Iwo, laaarọ Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, ni kabiesi ti kede pe ọmọ naa yoo maa jẹ Luwo Gbagida, Adewumi, Sultana, Fatimoh.

Ọba Akanbi ṣalaye pe Luwo Gbadiga lo bi Adekọla Telu to tẹ ilu Iwo do, o jẹ akinkanju, onigboya ati ọbabinrin akọkọ to ni afojusun rere kaakiri agbaye. Oun naa si ni obinrin akọkọ to jẹ Ọlọfin Adimula.

Leave a Reply