Ọmọ aṣofin ilẹ wa ku lẹyin ọsẹ meji to de lati Ukraine

Jọkẹ Amọri

Inu ibanujẹ nla ni ọkan ninu awọn aṣofin ipinlẹ Sokoto, Ọnọrebu Abibu Haliru Modachi, wa bayii. Eyi ko sẹyin bi ọkan ninu awọn ọmọ rẹ, Usaifa Modachi, ṣe ku lojiji lọsẹ keji ti wọn ko wọn de lati orileede Ukraine.

Akẹkọọ nipa imọ iṣegun ni ọmọkunrin yii, ileewe giga yunifasiti kan ti wọn n pe ni Zaporizhzhia State Medical University, to wa ni Ukraine lo n lọ.

Ipele aṣekagba ni ọmọkunrin naa wa nileewe ọhun, ti ki i baa si ṣe wahala to ṣẹlẹ laarin Ukraine ati Russia, ọmọkunrin yii ti n gbaradi fun idanwo aṣekagba rẹ ti iba sọ ọ di akọṣẹmọṣẹ oniṣegun oyinbo.

Ohun to ba ni lọkan jẹ nipa iku ọmọkunrin naa ni pe lati bii ọdun mẹta sẹyin to ti kuro nile, to ti lọ si ileewe giga naa ni Ukraine, ko ti i wale. O jọ pe erongba rẹ ni lati pari iwe rẹ patapata ko too di pe o pada sile pẹlu iwe ẹri rẹ. Iwe ẹri naa ni ko duro gba ti wahala fi de. Bo ṣe pada sile lo bẹrẹ aisan ranpẹ to pada gba ẹmi rẹ yii.

Baba Usaifa ti fọrọ mọ Ọlọrun lọkan ṣa o. O ni oun dupẹ lọwọ Ọlọrun, Ọlọrun lo fun awọn, Oun naa lo si gba a, ko si ariyanjiyan ninu eleyii. ‘To ba ṣe pe Ukraine lo ku si ni, oriṣiiriṣii ọrọ ni awọn eeyan iba maa sọ nipa iku rẹ, bi awọn kan ba ti n sọ pe wọn yinbọn pa a ni lawọn mi-in iba maa sọ pe o ku sinu ijamba ọkọ ni. Ṣugbọn a dupẹ lọwọ Ọlọrun pe o ku sọdọ wa.

‘‘Bakan naa lo dupẹ lọwọ ijọba ipinlẹ Sokoto fun atilẹyin wọn lati ri i pe wọn ṣeto to yẹ lati ko awọn ọmọ naa wale.

Leave a Reply