Ọmọ Akunyili ti wọn pa ni: Emi ati baba mi ṣi sọrọ lo ku ọla to maa ku

Faith Adebọla

Ọrọ idaro to n ti ẹnu Abilekọ Chidiogo Akunyili-Parr, ọkan lara awọn ọmọ oloogbe, Dokita Chike Akunyili, jade, lasiko yii fi bi ibanujẹ iku baba wọn to jade laye lojiji ṣe ka a lara to han.

Dokita Akunyili, ọkọ Ọga agba ajọ NAFDAC tẹlẹ nilẹ wa, Ọjọgbọn Dora Akunyili, lawọn kan ṣeku pa lọjọ Iṣẹgun, Tusidee ọsẹ yii, lagbegbe Afor Nkpor, nijọba ibilẹ Ariwa Ndemili, ipinlẹ Anambra, bo ṣe n dari bọ lati ibi to ti lọọ gba ami-ẹyẹ kan ti wọn fi da iyawo rẹ to ti doloogbe naa lọla.

Chidiogo lọ sori ikanni Instagiraamu rẹ, o si kọ awọn ọrọ wọnyi sibẹ, o ni:

“Ubuntu (ọkan lara orukọ baba rẹ) tumọ si ‘bo ṣe n ṣe yin lo n jẹ ko ṣẹlẹ si mi’. To ba jẹ loootọ ni itumọ orukọ yii, a jẹ pe ọkunrin to tawọ si adọdọ ibọn rẹ, to si yin in lu ọ lẹẹmeji, bi aye ṣe ri, bi ayika rẹ si ṣe ri, lo fara han ninu ibinu rẹ, iwa aitọ ati iwa ọdaran to hu yẹn.

Ani to ba jẹ loootọ ni itumọ orukọ yii, a jẹ pe gbogbo bi baba mi ṣe n pọkaka iku, ti ẹmi fẹẹ bọ lẹnu ẹ yẹn ṣẹlẹ lati fi bi ara ṣe n ni orileede wa to, bi orileede wa ṣe n pọkaka iku han ni.”

Chidiogo, to gbe oriṣiiriṣii fọto toun ati baba rẹ ya papọ sori ikanni naa, sọ pe iku baba oun yii yẹ ko mu kawọn eeyan ji giri si iṣoro aabo to mẹhẹ lorileede yii, ki wọn si wo ọna to daa ju lati yanju ẹ.

Ọmọ naa tun sọ pe oun ati oloogbe yii sọrọ ni alẹ ọjọ to ṣaaju iku rẹ, toun o si mọ pe ọrọ to maa ba oun sọ kẹyin niyẹn.

O ni nigba toun ati oloogbe naa n sọrọ, o bi oun leere pe igba wo loun maa bimọ le ọmọ ọwọ oun yii, tori oun fẹẹ fun un lorukọ kan toun ti n tọju pamọ tipẹ. O ni baba oun lo sọ ọmọ toun n tọ lọwọ ni Mmesomma, eyi to tumọ si ‘ohun to rẹwa nikan l’Ọlọrun n ṣe, bẹẹ la sọrọ nipa ipo ti Naijiria wa bayii’.

O pari ọrọ rẹ pe: “A le ti gba ọna ọtọọtọ bayii o… ṣugbọn ọna to mu iku oro bii eyi wa, to si n ṣẹlẹ si ọpọ eeyan, ko daa rara.”

Leave a Reply