Florence Babaṣọla
Oluwoo tilu Iwo, nipinlẹ Ọṣun, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi, ti sọ pe ẹnikẹni ninu iran Yoruba ti ko ba fara mọ erongba Bọla Hammed Tinubu lati di aarẹ orileede yii lọdun 2023, ọmọ ale ni.
Nibi ifilọlẹ ẹgbẹ kan ti yoo wa fun ipolongo ibo aarẹ fun Tinubu, eleyii ti wọn pe ni South West Agenda for Asiwaju Bola Hammed Tinubu 2023 (SWAGA), to waye niluu Oṣogbo lọjọ Iṣẹ́gun,Tusidee, ọsẹ yii, ni Oluwoo ti sọ pe egun kan ṣoṣo to wa lori iran Yoruba ni ki wọn maa fi ẹnu tẹnbẹlu ẹnikẹni to ba ti fẹẹ goke agba, oun si ti ṣetan lati mu egun naa kuro.
Ọba Adewale ṣalaye pe, “A ti ṣetan lati mu atunṣe ba awọn aṣiṣe atẹyinwa, egun ni ninu iran wa pe a ki i mọyii awọn aṣaaju ti wọn ti laami-laaka nilẹ wa, a si gbọdọ ṣiṣẹ papọ lati mu egun naa kuro.
“Aṣiwaju Bọla Hammed Tinubu jẹ adari to ni arojinlẹ, adari ti Ọlọrun fi ọgbọn atinuwa jinnki, o ran ogunlọgọ awọn eeyan lọwọ lati depo nla kaakiri orileede yii, ṣugbọn dipo ka yin in, awọn ika laarin wa la n gbe gẹgẹ. Ẹni to ba mọ pe Tinubu ko le ṣe aarẹ, ko darukọ ẹni to ro pe o le ṣe e ninu iran Yoruba.
“Ọlọrun ti yan an, oun ni Awolọwọ asiko wa yii, gbogbo wa la gbọdọ fọwọsowọpọ pẹlu rẹ, iran wa ni, Yoruba gbọdọ ronu, ki i ṣe ọrọ ẹgbẹ oṣelu lo wa nilẹ yii, ọrọ iran wa ni, ọmọ-ale Yoruba ni ko si ni tẹle e lọdun 2023”
Bakan naa ni Olojudo ti Ido-Ọṣun, Ọba Aderẹmi Adedapọ, sọ pe awọn amuyẹ to mu ki gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ, Aṣiwaju Bọla Hammed Tinubu, yatọ si awọn aṣaaju to ku lo fa a to fi yẹ ki gbogbo iran Yoruba fi ibo wọn gbe e wọle gẹgẹ bii aarẹ Naijiria lọdun 2023.
O ni ẹni to jẹ oloootọ, to si ṣe e fọkan tan, ni Tinubu, bẹẹ lo si ti la ipa rere ti ko ṣee gbagbe ninu aye ọpọlọpọ eniyan lorileede yii ati lẹyin odi; yala lasiko to jẹ gomina ati lẹyin to kuro nibẹ.
O fi kun ọrọ rẹ pe, “Emi o ki i ṣe oloṣelu, ṣugbọn ohunkohun to ba tọna ni mo maa n tẹle. Emi o ro pe a ti ni iru adari to ni awọn amuyẹ bii ti Tinubu nilẹ Yoruba, gbogbo wa si gbọdọ ri i pe asiko tiwa niyii, ẹ jẹ ka gbaruku ti i, ko si di aarẹ orileede yii lọdun 2023”
Ninu ọrọ alaga SWAGA nipinlẹ Ọṣun, Ọnarebu Ayọ Omidiran, o ṣalaye pe ko si ẹni ti ko mọ pe iha Iwọ-Oorun Guusu orileede yii jẹ ọkan gboogi ninu ẹkun to gbe ijọba tiwa-n-tiwa ro ni Naijiria, o si ti to akoko fun gbogbo iran Yoruba lati fi agbajọwọ ṣọya bayii.
Omidiran ni ki i ṣe Aṣiwaju Tinubu lo ran awọn lati gbe ẹgbẹ naa kalẹ, ṣugbọn ṣe ni gbogbo awọn lookọlookọ lorileede yii jokoo papọ, ti wọn si ri i pe Tinubu ni ipo naa tọ si.”
Ni ti alakooso gbogbogbo ẹgbẹ naa, Sẹnetọ Dayọ Adeyẹye, o ni awọn tete bẹrẹ ipolongo naa lati le jẹ ki gbogbo iran Yoruba ji, ki wọn mọ pe awọn ni anfaani lasiko yii, bẹẹ ni pe ẹni to kunju osunwọn ni Tinubu.
O wa ke si gbogbo awọn eeyan Iwọ-Oorun Guusu orileede yii lati ma ṣe faaye gba ẹnikẹni tabi ohunkohun ti yoo mu iyapa ba erongba naa. Ki wọn fọwọsowọpọ, ki wọn si fi ohun kanṣoṣo sọrọ lori ohun ti wọn fẹ.
Lara awọn ti wọn wa nibẹ ni iyawo gomina ipinlẹ Ọṣun, Alhaj Kafayat Oyetọla, alaga ẹgbẹ APC l’Ọṣun, Ọmọọba Gboyega Famọdun, aṣoju orileede Naijiria ni Mexico, Adejare Bello, Timi Ẹdẹ, Aragbiji ti Iragbiji, Alapomu ti Apomu ati bẹẹ bẹẹ lọ.