Faith Adebọla
Afaimọ lawọn afurasi ọdaran mẹta tọwọ tẹ yii ko ni i pẹ lẹwọn bii ọbọ latari bi wọn ṣe fẹsun kan wọn pe wọn n digunjale, wọn lọọ fọ ọsibitu ti wọn kọ fawọn alaisan, wọn ko dukia olowo iyebiye ibẹ ta, bẹẹ ni wọn tun n ṣẹgbẹ okunkun.
Ọga agba ẹṣọ alaabo Amọtẹkun nipinlẹ Ogun, Ọgbẹni David Akinrẹmi, lo sọrọ yii di mimọ ninu atẹjade kan to fi lede lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹta yii.
Akinrẹmi ni ọkan ninu awọn afurasi yii, Kẹhinde Ogunjẹmbọla, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn, lọwọ kọkọ tẹ lọjọ kejila, oṣu Kẹta yii, nigba ti obinrin kan, Kẹhinde Banjoko, waa fẹjọ sun lọfiisi awọn pe awọn fọlefọle kan ti jalẹkun ile oun lasiko toun rinrin-ajo lọ s’Ekoo lọsẹ to kọja, ko too de ni wọn ti sọ ile ẹ to wa l’Ojule keji, Opopona Ẹfunyẹla, n’Ipẹru, ipinlẹ Ogun, di korofo.
Lara ẹru ti wọn ko ni ẹrọ amunawa ti wọn n pe ni jẹnẹretọ, doro afẹfẹ gaasi idana ẹ, faanu oniduuro, timutimu to fi n sun, rọọgi to tẹ silẹ, atawọn ẹru mi-in, niṣe ni wọn gba gbogbo yara ẹ mọ fefe, wọn lawọn ẹru ti wọn ji ọhun to ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Naira.
Lẹyin tawọn ẹṣọ Amọtẹkun fimu finlẹ diẹ, olobo ta wọn, ni wọn ba mu Kẹhinde, bi wọn si ṣe mu un, ko jampata, ko si ja wọn niyan, wọn ni pẹlu irọrun lo fi jẹwọ pe loootọ loun lọọ fọle obinrin naa, amọ ki i ṣe oun nikan, o lawọn meji lawọn ṣiṣẹ buruku naa, ṣugbọn ẹnikeji oun ti sa lọ ni tiẹ. Lẹyin naa lo mu wọn de ọdọ ẹni ti wọn ta awọn ẹru ole ọhun fun, Lawal Aliu, ni wọn porukọ ẹ, wọn si ba awọn ẹru naa lọdọ ẹ loootọ, ni wọn ba fi pampẹ ofin mu un, tori agbepo-laja ko jale bii ẹni to gba a silẹ lọwọ ẹ.
Lasiko ti iwadii n tẹsiwaju laṣiiri tun tu pe Kẹhinde yii kan naa lo ṣaaju awọn afurasi adigunjale kan ti wọn lọọ fọ ọsibitu awọn alabiyamọ tijọba ṣẹṣẹ kọ pari sagbegbe Ipẹru Rẹmọ. O jẹwọ fawọn ọtẹlẹmuyẹ pe oun atawọn kan to ni wọn ti sa lọ, ni awọn jọọ ṣakọlu si ọsibitu naa.
Lara ẹru ti wọn ji ko nibẹ ni tẹlifiṣan Hisense inṣi mẹtalelogoji mẹfa, tẹlifiṣan Bruhm, inṣi marundinlaaadọrin meji, firiiji Bruhm mẹta, firiiji Midea kan, awọn faanu Lontor oniduuro to n lo batiri mẹta atawọn nnkan pẹẹpẹẹpẹẹ mi-in. Aropọ owo awọn ẹru yii jẹ miliọnu mẹta Naira, gbogbo ẹ si ni wọn ti ri gba pada nibi ti wọn lọọ ko o pamọ si, iyẹn ẹni ti wọn lawọn fẹẹ ta wọn fun.
Nigba tawọn Amọtẹkun tubọ tọwọ bọ Kẹhinde lẹnu lo jẹwọ pe ọmọ ẹgbẹ okunkun loun, o loun atawọn ọrẹ oun tawọn jọ n digunjale n ṣẹgbẹ okunkun papọ ni.
Akinrẹmi ni awọn ti pari eto lati taari awọn afurasi ọdaran yii atawọn ẹru ẹlẹru ti wọn ji si olu-ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, ki wọn le tubọ ṣewadii bo ṣe tọ, ki wọn si foju wọn bale-ẹjọ.
Bakan naa lo lawọn ṣi n dọdẹ awọn ẹmẹwa Kẹhinde to sa lọ, oun si gbagbọ pe ẹgbẹrun Saamu wọn ko le sa m’Ọlọrun lọwọ.