Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Iya ati baba kan naa lo bi Okiki Mulero, Micheal Mulero ati Joseph Mulero, awọn mẹtẹẹta ni wọn ti wa latimọle bayii, nitori wọn lu fijilante So-Safe kan torukọ ẹ n jẹ Ṣẹgun Godfrey Barde pa l’Aṣero, niluu Abẹokuta.
Ọjọ Keresimesi to kọja yii ni wahala ṣẹlẹ, nigba ti Okiki Mulero to n ṣiṣẹ ọkada wiwa fẹẹ wọ Ẹsiteeti OGD, l’Aṣero, to si jẹ pe o gbe ju eeyan kan lọ.
Ofin Ẹsteeti naa ni pe ọlọkada ti yoo ba wọbẹ ko gbọdọ gbe ju eeyan kan ṣoṣo lọ, eyi lo fa a ti awọn ọlọdẹ to n ṣọ ẹnu ọna ibẹ ko ṣe jẹ ko wọle.
Ai jẹ ko wọle naa lo bi Okiki, ẹni ọdun mẹtalelogun, ninu, n lo ba pe awọn aburo rẹ mejeeji ti i ṣe Micheal ati Joseph, pe ki wọn waa kun oun lọwọ lati koju awọn ọlọdẹ to jẹ oṣiṣẹ So-Safe naa.
Bi wọn ṣe de ni wọn yọ igi, ti wọn bẹrẹ si i lu awọn ẹṣọ meji to n ṣiṣẹ wọn jẹẹjẹ naa.
Nibi ti wọn ti n lu wọn ni igi ti ba Ṣẹgun Godfrey Barde nibi to lagbara, bẹẹ lọkunrin naa ṣubu lulẹ, ti ko le dide mọ. Wọn sare gbe e lọ sọsibitu, sugbọn nibi ti wọn ti n tọju rẹ lo ku si.
Awọn ọmọ iya mẹta yii jẹwọ nigba tọwọ tẹ wọn pe awọn lawọn lu Ṣẹgun to fi ja siku.
Ẹka ti wọn ti n gbọ ẹjọ apaayan ni awọn mẹtẹẹta wa bayii, gẹgẹ bi CP Ajogun Edward ṣe paṣẹ.