Ibrhim Alagunmu, Ilọrin
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kwara ti kede pe ọwọ awọn ti tẹ awọn afurasi mẹta kan lori fifọmọ ṣowo ẹru lagbegbe Oko-Olowo, niluu Ilọrin, pẹlu awọn ọmọ mọkanlelogoji (41).
Awọn obinrin mẹrin naa ni: Musa Ayuba, ẹni ọdun mẹrinlelogoji, Jeremiah Muda, ẹni ọdun marunlelọgbọn,, ati Luka Ayuba, ẹni ọdun mẹtadinlogoji, awọn ọmọ wẹwẹ ọkunrin atobinrin mọkanlelogoji ni wọn ba lọwọ wọn. Ọmokunrin mejilelogun, obinrin mọkanlelogun, lati Abule Bangi si Kotongura, nipinlẹ Niger, ni wọn to awọn ọmọ naa tọjọ ori wọn ko ju ọdun marun-un si mẹẹẹdogun lọ wa siluu Ilọrin.
Ninu atẹjade kan ti Alukoro ọlọpaa ni Kwara, Ọkasanmi Ajayi, fi sita to tẹ ALAROYE lọwọ lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹrinla, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, lo ti salaye pe igbiyanju iṣẹ awọn ọlọpaa lo jẹ ki ọwọ tẹ awọn afurasi naa ti wọn ni awọn n ko awọn ọmọ naa bọ lati ipinlẹ Niger. Wọn ni pasitọ kan ti yoo maa tọ awọn naa ni ileewe niluu Ilọrin, ni awọn fẹ́ẹ́ lọwọ ko wọn fun.
Ajayi ni awọn eeyan naa ṣi wa ni akata ileeṣẹ ọlọpaa bayiii. O fi kun un pe awọn ti pe ajọ to n ri si ọrọ awọn obinrin nipinlẹ Kwara, wọn si ti n gbiyanju lati pe obi awọn ọmọ ọhun lẹyọkọọkan. O fi kun un pe lẹyin ẹkunrẹrẹ iwadii lawọn yoo foju awọn afurasi naa ba Ile-ẹjọ.
Kọmisanna ọlọpaa ni Kwara CP Paul Odama, rọ gbogbo awọn obi atawọn alagbatọ pe ki wọn yee fi ọmọ wọn silẹ fun awọn ti yoo maa tan wọn lati fi wọn ṣowo ẹru.