Monisọla Saka
Ajọ to n ri si eto irinajo lọ si ilẹ mimọ Mẹka, ni Naijiria (National Hajj Commission of Nigeria), ti kede iku Hasiya Aminu to wa lati ipinlẹ Kaduna gẹgẹ bii ọkan lara awọn to ku sibi ti wọn ti n ṣiṣẹ Oluwa ni Saudi Arabia. Gẹgẹ bi awọn alaamuleti rẹ ṣe sọ, wọn ni, lẹyin ti wọn de pada lati ibi ti wọn ti lọọ gun oke Arafa lobinrin naa sun ti ko si ji mọ.
Dokita Usman Galadima, to jẹ ọga patapata ati adari fun eto ilera awọn ọmọ Naijiria (Nigerian Medical Mission) ṣalaye fun Ajọ akoroyin jọ ilẹ Naijiria (NAN) pe, ninu ayẹwo ti awọn ṣe, ko si ohun kan pato bayii ti awọn le tọka si pe o pa obinrin naa.
O fi kun un pe awọn ti fi ọrọ iku Hasiya Aminu to awọn mọlẹbi ẹ leti, wọn yoo si sin in ni ilana ofin ẹsin Islaamu.
Ẹni akọkọ ninu awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria to kọkọ ku lọsẹ to kọja ni Hajiya Aisha Ahmed lati Keffi, nipinlẹ Nassarawa, lẹyin aisan ranpẹ, ti wọn si ti sin oku ẹ si ilu Mẹka.
Hasiya Aminu to ku lẹyin ti wọn de lati oke Arafa yii lo mu ki awọn ti wọn ti padanu ẹmi wọn si ilu Mẹka di meji.
Dandan ni ki awọn ti wọn ba lọ si Mẹka fun iṣẹ Haji lọ si ori oke Arafa yii, ki iṣẹ Haji wọn le ba a pe.
Awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria ti wọn lọ si orilẹ-ede Saudi Arabia fun iṣẹ naa wa lara awọn eeyan ti wọn le ni miliọnu kan kaakiri agbaye ti wọn waa ṣiṣẹ Haji ọdun 2022.