Ọmọ ni Rẹmi fẹẹ lọọ gbe nileewe ti omi fi gbe e lọ l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọlọkada kan, Aderẹmi Adelalu, la gbọ pe omi gbe lọ lasiko to fẹẹ lọọ gbe ọmọ rẹ nile-iwe lalẹ ọjọ Aje, Mọnde ọsẹ ta a wa yii.

Iṣẹlẹ yii waye lasiko arọọrọda ojo kan to bẹrẹ ni nnkan bii aago mẹta ọsan, ti ko si da titi tilẹ ọjọ naa fi su.

Ninu alaye ti ẹnikan to porukọ ara rẹ ni Ọmọniyi ṣe fun akọroyin wa, o ni, iyawo Rẹmi lo pe oun sori aago lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, to si ni oun ko ri ọkọ oun ko pada wale latigba to ti dagbere pe oun fẹẹ lọọ gbe ọmọ awọn nileewe.

Isẹ ọkada ni Rẹmi n ṣe gẹgẹ bii alaye to ṣe fun wa, iwaju ọgba ile-ẹkọ olukọni agba Adeyẹmi to wa niluu Ondo ni gareeji rẹ wa, koda ọpọlọpọ ọdun ni wọn lo fi jẹ alaga ẹgbẹ awọn ọlọkada ẹka ti Adeyẹmi.

O ni ọlọkada kan lo ba ṣe adehun lati maa gbe ọmọ rẹ lati ile-iwe awọn obinrin to wa loju ọna Ile-Ifẹ, ti yoo si waa ja a siwaju ọgba Adeyẹmi nibi ti oun funra rẹ ti n ṣiṣẹ.

Ọmọbinrin naa lo fẹẹ lọọ sare gbe nibi ti wọn ja a si nirọlẹ ọjọ yii to fi  kori bọnu ojo to n rọ lọwọ.

Dipo ti iba si fi duro ki omi nla to ti gori afara odo kekere kan to wa lagbegbe Oke-Ọdunwo, nibi to fẹẹ gba kọja fa diẹ, ṣe lo gbe ọkada rẹ wọnu rẹ leyii to ṣokunfa bi omi ọhun ṣe wọ ọ lọ.

Aarọ ọjọ kutukutu ọjọ keji lo ni iyawo rẹ pe oun, to si ni oun ko ri ọkọ oun ko wale waa sun lati ana to ti jade nile pe oun fẹẹ lọọ gbe ọmọ.

O ni ibi tí oun ti n ronu ohun to le sẹlẹ lọwọ ni ẹnikan ti pe oun sori aago pe wọn ri ọkada ẹnikan ti omi gbe lọ l’Oke-Ọdunwo.

Ọgọọrọ awọn eeyan to ba leti bebe odo naa ni wọn darapọ mọ ọn lati wa gbogbo inu omi ọhun wo boya wọn le ri Rẹmi nibi to ha si, ṣugbọn awọn ko ri ẹni to jọ ọ.

Ọsan ọjọ kẹta ti i ṣe Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, ni wọn too pada ri oku rẹ lagbegbe kan ti wọn n pe ni Ogedemgbe, nitosi Ọna Abayọ, Lipakala, Ondo.

Ọmọniyi sọ ninu ọrọ rẹ pe ki i ṣe igba akọkọ ree ti iru iṣẹlẹ yii maa waye nibi odo naa, o ni ko si ọdun kan ti odo ọhun ki i gbe eniyan lọ nigbakuugba to ba ti kun bo afara ti wọn ṣe sori rẹ mọlẹ.

Leave a Reply