Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ẹwọn ọdun marun-un nile-ẹjọ Majisireeti kan sọ ọmọ ọdun mẹẹẹdogun kan atawọn ẹgbẹ ẹ si nitori ti wọn sa lagọọ ọlọpaa, ti wọn si tun ba dukia ijọba jẹ.
Niwaju Adajọ Abayọmi Ajala ti ile-ẹjọ Majisireeti kan niluu Oṣogbo ni ọmọ ọdun mẹẹẹdogun yii ti kọkọ foju han nile-ẹjọ lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu keje, ọdun yii, pẹlu awọn ẹlẹgbẹ ẹ yii, Abeeb Adeleke, ọmọ ogun ọdun, Ṣẹgun Ishọla, ọmọ ọdun mejidinlogun, Maliq Adewale, ̀ọmọ ọdun mejidinlogun.
Ẹsun mẹta ni wọn ka si wọn lẹsẹ, wọn ni wọn sa mọ ọlọpaa lọwọ, wọn tun gbimọ-pọ huwa ọdaran, bẹẹ ni wọn ba dukia ijọba jẹ.
Ọlọpaa to wa nidii ẹjọ awọn ọmọ naa, Kayọde Adeoye, sọ pe, ni deede aago mẹta oru ni wọn sa kuro lagọọ ọlọpaa Dugbẹ, niluu Oṣogbo, lẹyin ti wọn ba ilẹkun onirin to wa lagọọ ọlọpaa naa jẹ, ti wọn si tun ja orule teṣan danu ki wọn too fẹṣẹ fẹ ẹ lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu keje.
Lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu keje, ni wọn ko wọn wa siwaju adajọ lẹyin tọwọ pada tẹ wọn, nibẹ lawọn mẹtẹẹta ti bẹbẹ pe awọn ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan awọn. Bakan naa ni agbẹjọro wọn, Adedoyin Ajewọle, bẹ adajọ ko ṣiju aanu wo wọn, ki idajọ wọn ma le ju fun wọn.
Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹfa, gan-an ni adajọ paṣẹ pe ki wọn sare lọọ faṣọ penpe roko ọba lọgba ẹwọn, wọn si gb̀ọdọ lo ọdun marun-un marun-un tabi ki wọn sanwo itanran ẹgbẹrun mẹsan-an naira ẹnikọọkan pẹlu ẹgba mẹfa-mẹfa nibadi wọn.