Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
‘Loootọ ni mo n jale, ogun idile lo n ja mi, emi naa mọ pọrọ mi ki i ṣoju lasan nitori pe mi o ti i ju bii ọmọ ọdun meje pere lọ ti mo ti n jale n’Igbara-Oke to jẹ ilu abinibi mi.”
Eyi lawọn ọrọ aro to n jade lẹnu ọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn kan, Gbenga Kikiowo, lasiko ti wọn n ṣafihan oun atawọn ẹgbẹ rẹ kan tọwọ tẹ fun ẹsun idigunjale l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, ni olu ileeṣẹ awọn ọlọpaa to wa loju ọna Igbatoro, Alagbaka, l’Akurẹ.
Kọmisanna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Bọlaji Salami, ṣalaye fawọn akọroyin lasiko to n ṣafihan awọn afurasi ọhun ni olu ileesẹ wọn to wa ni Alagbaka, pe Gbenga ati ọrẹ rẹ kan ti wọn n pe ni Aladeloye Tọpẹ, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn, lọwọ tẹ lagbegbe Oke-Aro, ni nnkan bii aago mẹsan-an alẹ ọjọ kẹrinlelogun, osu karun-un, ọdun 2021.
O ni ibi tawọn ikọ adigunjale ẹlẹni meji naa ti fẹẹ lọọ digunjale lawọn eeyan kan ti sare pe awọn, ti awọn si lọọ fi pampẹ ofin gbe awọn mejeeji.
Ọpọlọpọ iṣẹ ibi ti wọn ti ṣe sẹyin lo ni wọn ti jẹwọ rẹ lasiko ti awọn n fọrọ wa wọn lẹnu wo.