Odidi mọlẹbi kan jẹ majele mọ ounjẹ, ni mẹwaa ba ku ninu wọn ni Kwara

Ibrahim Alagunmu, Ilorin

Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni awọn mọlẹbi kan jẹ majele mọ ounjẹ alẹ niluu Biogberu, lagbegbe Gwanara, nipinlẹ Kwara, ti eeyan mẹwaa si dagbere faye.

ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago mẹwaa alẹ ọjọ Aje ni wọn jẹ ounjẹ alẹ ọhun, eyi ti majele ti wa ninu rẹ ni ile olori awọn Fulani to wa ni agbegbe Biogberu ti wọn si gbabẹ lọ sọrun alakeji.

Ohun tawọn tọrọ naa ṣoju wọn sọ ni pe olori awọn Fulani ọhun lọ sọdọ oniṣegun rẹ, Musa, pe ohun nilo oogun agbele-pọta, baba oloogun si gbe oogun naa fun un pe ki wọn da a sinu ounjẹ, ki wọn jẹ ẹ mọ ounjẹ. Ṣugbọn wọn ṣi oogun naa lo, ọtọ ni bi Musa to jẹ baba oloogun ṣe ni ki wọn lo o, ọtọ ni bi wọn ṣe lo o. Ni inu ba bẹrẹ si i run gbogbo wọn pẹlu oniruuru inira.

Awọn mẹfa ni ko ku lalẹ ọjọ Aje tiṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ, ti wọn si gbe wọn lọ sọsibitu Bukari Kawo Memorial, to wa ni Gwanara, sugbọn awọn naa pada ku ni owurọ kutu ọjọ Iṣẹgun, Tusidee ọṣẹ yii.

Wọnyii ni orukọ awọn to ba iṣẹlẹ naa lọ : Ibou oun ni baba, Bake ni iya, orukọ awọn ọmọ ni, Juli, Sidiq, Banna, Yon, Zenab, Denbo ati Junbo.

Agọ ọlọpaa to wa ni ilu Gwanara ti tẹwọ gba iṣẹlẹ naa, wọn si ni awọn yoo ṣe ẹkunrẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ ọhun.

Bakan naa ni Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Ọkasanmi Ajayi, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o ni awọn yoo gbe igbesẹ to ba tọ lori iṣẹlẹ naa.

 

Leave a Reply